IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 13 December 2017

Owo te Tomiwa to fee ji foonu ninu soosi

Tolulope Emmanuel, Osogbo

Olatomiwa Badmus to je omo odun merinlelogun lo ti foju bale ejo majiatreeti ilu Modakeke bayii lori esun wi pe o ji foonu.

Nnkan aago mejo ale ku die la gbo pe Tomiwa lo sinuu soosi God's Love Tabernacle to wa lagbegbe Aserifa nilu Modakeke to si fee ji foonu kan nibe.

Ojo kokanla osu kokanla odun yii ni Tomiwa huwa naa gege bi agbejoro to soju funleese olopa, Sajenti Ona Glory se so funle ejo.

Sugbon ojo gbogbo ni tole, ojo kan ni toninnkan, eleyii lo difa fun bi owo se te Tomiwa ninui soosi ohun lojo naa, ti won si fa a le awon agbofinro lowo.

Nigba ti won mu un de ago olopa lo jewo iwa naa, idi si niyii to fi dero ile ejo. Esun ole jija ni won fi kan an, o si so pe oun ko jebi esun naa.

Sajenti Ona so pe iwa ti Tomiwa hu ohun lodi, bee lo si nijiya nla labe ofin iwa odaran tipinle Osun.

Ninu idajo re, Majistreeti Bose Awosan faaye beeli sile fun un pelu egberun lona ogbon naira ati oniduro meji ni iye kannaa.

O ni okan lara awon oniduro naa gbodo ni ile (landed property) lagbegbe ile ejo, ki awon agbofinro si mo adireesi won.

No comments:

Post a Comment