Lọọja Clement Adesuyi Haastrup lati ile Bilaro Oluodo Ruling House ni wọn ti mu gẹgẹ bii Ọwa Obokun Ajimọkọ Kẹta ni ilẹ Ijeṣa bayii.
Nibi eto to waye ninuu sẹkiteriati Iwọ-oorun ilu Ileṣa lonii ni Adeṣuyi ti gbegba oroke laarin awọn oludije mẹsan ti wọn fi ifẹ han si itẹ Ọwa Obokun.
Awọn afọbajẹ, awọn Iwọra mẹfa ri wọn jẹ Obaala, High chief Ibitoye, Ogboni Ipole, Oba Omokehinde Oyeleye, Ogboni Ijebu-jesa, Oba Olufemi Agunsoye ( Elegboro), Ogboni Ibokun, Oba Festus Awogboro, Ogboni Ilesa, High Chief Saka Fapohunda, Oba Odo of Ilesa, ati Agba Ijeṣa meje; Risawe of Ilesa, High Chief Adefioye Adedeji, Lejoka of Ilesa, High Chief Omoniyi Ojo, Lejofi, High Chief Adebusoye Onigbogi, Arapate of Ilesa, High Chief Oluwagbemiga Fadunsin Igbarool, Loro of Ilesa, High Chief Lekan Folorunso, Odole of Ilesa, High Chief Bola Orolugbagbe ati Ọgbẹni Abimbola Aluko (ti wọn yan lati ṣojuu Saloro of ilesa) ni wọn kopa ninu eto naa.
No comments:
Post a Comment