Orukọ awọn oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun pẹlu awọn igbakeji wọn gẹgẹ bi ajọ INEC ṣe gbe e jade niyii:
Sẹnetọ Ademola Adeleke mu Ọmọọba Kọla Adewusi gẹgẹ bii igbakeji labẹ asia ẹgbẹ Accord.
All Progressives Congress fa Bola Oyebamiji ati Tunde Olatunji kalẹ bii gomina atigbakeji rẹ.
Action Democratic Party gbe Adeagbo Yemisi ati Atanda Babatunde kalẹ, nigba ti ẹgbẹ Young Peoples Party fa Ogunṣakin Enoch ati Oyetọla Taye silẹ.
Adesọji Maṣilo ati Aresa Adenike ni Boot Party fa kalẹ, nigba ti NNPP fa Adeleke Adewale pẹlu Adeyera Adesola kalẹ.
African Action Congress fa Esan Abeeb ati Bello Muideen kalẹ, Olanrewaju Farinloye ati Fadahunsi Olaniyi ni yoo si ṣoju ẹgbẹ Action Alliance.
Najeem Salam ni oludije funpo gomina ninu ẹgbẹ African Democratic Congress, nigba ti Popoola Tajudeen.
Adewale Adebayo ni ti ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement pẹluu Jimoh Naheem.

No comments:
Post a Comment