IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 10 February 2026

Adeoti darapọ mọ ẹgbẹ Accord, o sọrọ nipa Arẹgbẹṣọla


Akọwe funjọba ipinlẹ Ọṣun nigba kan ri, Alhaji Moshood Adeoti, ti kede pe oun ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Accord bayii.


O ni lootọ gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu ni wọn wa ba oun lati darapọ mọ wọn, ṣugbọn oun pinnu lati lọ sinu ẹgbẹ Accord nitori ẹni ti gbogbo ilu fẹ ni Gomina Ademọla Adeleke.


Adeoti, ẹni to jẹ ọkan lara awọn to duro pẹlu gomina ijẹta l'Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla, sọ pe oun pinnu lati kuro lẹyin Arẹgbẹṣọla lẹyin ti oun atawọn ọmọlẹyin oun fẹnu ko lorii rẹ.


O ni oun ṣe ọpọlọpọ wahala fun Ọgbẹni Arẹgbeṣọla nigba to fi maa wọpinlẹ Ọṣun, ṣugbọn ṣe lo fi ṣu oun.

No comments:

Post a Comment