Ẹnjinia Israel Ajibọla Famurewa to ti figba kan ri ṣoju awọn eeyan Ila Oorun Ọṣun nile igbimọ aṣofin apapọ, ti sọ pe ibanujẹ nla ni iku alakoso eto gbogbo fun ẹgbẹ oṣelu APC ̀lorileede yii, Dokita Abdulraif Adekunle Adeniji, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Natty Kongo, jẹ.
O ni oloṣelu to ni afayaran ati oṣiṣẹ ijọba to mu iṣẹ rẹ lọkunkundun ni ọkunrin ọmọbibi ilu Ileefẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti Famurewa fọwọ si lo ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn ajinigbe ṣe da ẹmi ọkunrin naa legbodo, o si pe fun idajọ to nipọn lori awọn ti wọn lọwọ ninu iku rẹ.
O ni aṣaaju to ṣe e ṣawokọṣe, onirẹlẹ eeyan ati ẹni to duro ti ẹgbẹ onitẹsiwaju ni Oloogbe Adeniji jẹ.
Famurewa mu un wa si iranti, oniruuru ipa ribiribi ti ọkunrin oloṣelu yii ko ninu aṣeyọri ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun ati lorileede Naijiria lati ọdun 1999 nigba to jẹ alaga funjọba ibilẹ Aaringbungbun Ifẹ.
Bakan naa lo tun yannayanna ojuse Adeniji lati mu idagbasoke ba ẹgbẹ wọn, to fi mọ ipa to ko laipẹ yii gẹgẹ bii alakoso ni Ila Oorun Ọṣun fun ikọ ipolongo ibo to gbe Aarẹ Bọla Tinubu wọle.
Hon. Famurewa sọ siwaju pe oun ko le gbagbe ipa Dokita Adeniji lasiko ipolongo ibo nigba ti oun jẹ oludije fun ipo Sẹnetọ ni Ila Oorun Ọṣun.
O waa gbadura pe ki Ọlọrun Allah tẹ Adeniji si afẹfẹ rere.
No comments:
Post a Comment