Alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Ọṣun, Hon. Sunday Bisi, ti sọ pe ko si iye ẹgbẹ oṣelu to le korajọ lati ṣiṣẹ papọ ninu idibo gomina Ọṣun lọdun 2026 ti wọn le fidi Gomina Ademọla Adeleke janlẹ.
Bisi ṣalaye pe ti idibo gomina ba waye l'Ọṣun lonii, ko si ibo kankan ti ẹgbẹ APC tabi ẹgbẹ oṣelu miran le ri nitori kaakiri ẹka nipinlẹ Ọṣun ni imọlẹ Adeleke ti n tan bayii.
Nibi eto kan ti ẹgbẹ awọn to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ iroyin nipinlẹ Ọṣun, League of Veteran Journalists, gbe kalẹ, eleyii ti wọn pe ni The Frontliners, ni alaga yii ti ṣalaye pe ko si nnkan ti ẹgbẹ oṣelu alatako fẹẹ lo lati fi polongo ibo fun awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lọdun 2026.
Ni ti ẹgbẹ oṣelu APC, o ni ewurẹ wọn kan n fẹsẹ halẹ lasan ni, ipinlẹ Ọṣun ti bọ lọwọ wọn. O ni ko sigba ti ẹgbẹ APC wa lori aleefa l'Ọṣun ti itura wa, lati aye Oloye Bisi Akande, inira ni ẹgbẹ naa maa n mu ba awọn araalu.
O sọ siwaju pe ko si ẹni to lọ kaakiri ipinlẹ Ọṣun bayii ti ko nii mọ pe iyatọ ti ba iwẹ-aarọ, ko si ẹka ti ọwọja iṣẹ idagbasoke oniruuru tijọba to wa lode bayii n ṣe ko de, bẹẹ ni awọn araalu ti mọ iyatọ laarin ẹgbẹ to fẹran wọn ati ẹgbẹ to n gbero inira fun wọn.
Ni ti wahala owo awọn ijọba ibilẹ, o ni ijọba ti kọ lẹta si gbogbo awọn to yẹ lati le yannayanna ọrọ naa daadaa, o si daju pe laipẹ ni ọrọ naa yoo yanju, ti awọn ojulowo alaga yoo pada si kansu, ti wọn a si maa gba owo to tọ si wọn latọwọ ijọba apapọ, ki wọn le tẹ siwaju ninu ojuṣe wọn.
Sunday Bisi dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun fun ifarada wọn latigba ti wahala ọrọ ijọba ibilẹ ti bẹrẹ, o si fi da wọn loju pe didun lọsan yoo so.
No comments:
Post a Comment