IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 26 June 2025

Hijrah 1447AH: Ijọba ipinlẹ Ọṣun kede ọlude


Lati ṣami ayẹyẹ ọdun Hijrah 1447AH, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede pe ọlude yoo wa fun gbogbo awọn oṣiṣẹ lọjọọ Furaidee ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun yii.


Ninu atẹjade kan ti kọmiṣanna fun ọrọ idile, Hon. Aderibigbe Kayọde Rasheed, fọwọ si nijọba ti sọ pe ọlude naa wa lati ṣami ibẹrẹ ọdun tuntun fun awọn musulumi.


Aderibigbe, lorukọ ijọba ipinlẹ Ọṣun, ki awọn musulumi ku ayẹyẹ naa, o si gbadura pe ki ayẹyẹ naa tubọ jẹ ki alaafia, igbega ati iṣọkan gbooro sii nipinlẹ Ọṣun.


O ke si awọn musulumi lati sa fun iwa to le fa iyapa tabi ikunsinu, ṣugbọn ki wọn ṣe ayẹyẹ naa ninu ayọ ati idunnu.

No comments:

Post a Comment