Amofin agba funpinlẹ Ọṣun, Oluwọle Jimi Bada, nipasẹ agbẹjọrọ rẹ, Musibau Adetunbi, SAN, ti jawọ ninu ẹjọ kan to gbe lọ sile ẹjọ to ga julọ lorileede yii lori ọrọ owo to tọ si awọn ijọba ibilẹ l'Ọṣun tijọba apapọ paka mọ.
Ọsẹ diẹ sẹyin nijọba ipinlẹ Ọṣun wọ amofin agba lorileede yii ati minisita fun eto iṣuna lọ sile ẹjọ to ga julọ lorileede yii, wọn ni latinu oṣu keji ọdun yii ti wahala ọrọ kansu ti bẹrẹ laarin ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC nijọba apapọ ko ti san owo to tọ sawọn ijọba ibilẹ l'Ọṣun fun wọn mọ.
Bada beere iru agbara tijọba apapọ ni lati paka mọ owo ti awọn ijọba ibilẹ to wa l'Ọṣun nikan laarin gbogbo ipinlẹ to wa lorileede Naijiria.
Ṣugbọn ninu esi ti amofin agba lorileede yii fi ranṣẹ si kootu, o ni irọ pata ni ẹsun naa nitori ijọba apapọ ko gbẹsẹ le owo awọn ijọba ibilẹ to wa l'Ọṣun.
Ọsẹ to kọja ni awuyewuye tun bẹrẹ lori ọrọ naa nigba tijọba ipinlẹ Ọṣun fẹsun kan banki apapọ orileede yii pe wọn fẹẹ san owo naa fun awọn alaga to jẹ ti ẹgbẹ APC.
Amọ ṣa, ninu awijare Amofin Oluwọle Bada, o ni ijọba gbe igbesẹ lati jawọ ninu ẹjọ naa niwọn igba tijọba apapọ ti sọ pe ko si owo naa nikawọ awọn. O ni ẹjọ ọhun ko niwulo mọ, paapaa, ni bayii ti aṣiri ti tu sawọn lọwọ pe ṣe ni wọn fẹẹ dọgbọn san an sinu asunwọn awọn oloṣelu kan ti wọn je gaba si kansu bayii.
O sọ siwaju pe idajọ kan ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ilu Akurẹ gbe kalẹ laipẹ yii ti fidi rẹ mulẹ pe iyọkuro nipo awọn alaga ẹgbẹ APC ṣi duro, awọn alaga tawọn araalu dibo yan lọjọ kejilelogun oṣu keji ọdun yii nikan si ni wọn lẹtọọ lati wa ni kansu.
Ni bayii, o ni awọn n duro de ohun ti amofin agba ati oluṣiro owo agba lorileede yii yoo sọ lẹyin ti awọn ti fi akọsilẹ idajọ ile-ẹjọ ranṣẹ si wọn.
No comments:
Post a Comment