Abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Rt Hon. Adewale Ẹgbẹdun ti kilọ fun awọn alakoso banki apapọ ilẹ wa lati maṣe ko owo to tọ sijọba ibilẹ l'Ọṣun fun awọn alaga ti wọn jẹgaba si kansu bayii.
Ninu ipinnu ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ṣe lonii Tọsidee, eleyii ti abẹnugan ka jade ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn alaga ti ajọ eleto idibo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun bura fun lọdun 2022, ṣugbọn ti idajọ ile ẹjọ ti le kuro nibẹ, ṣe tun n lọ kaakiri bayii, ti wọn n pe ara wọn ni alaga kansu.
Awọn aṣofin ṣalaye pe awọn alaga atawọn kanselọ ti awọn araalu dibo yan lọjọ kejilelogun oṣu keji ọdun yii nikan ni wọn jẹ ojulowo alaga labẹ ipin kinni, abala keje iwe ofin ọdun 1999.
Ipinnu wọn ọhun sọ siwaju pe 'Ofuutufẹẹtẹ ni ariwo ti awọn alaga idibo ọjọ kẹẹdogun oṣu kẹwaa ọdun 2022 n pa kaakiri pe ile ẹjọ kotẹmilọrun da awọn pada, ko lẹsẹ nilẹ, bẹẹ ni ko ridi joko labẹ ofin.
'Yiyan ẹnikẹni lati maa ṣakoso awọn ijọba ibilẹ lodi si ofin. Ile igbimọ aṣofin yii bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti banki apapọ ilẹ wa fẹẹ gbe lati san owo ijọba ibilẹ si asunwọn awọn ti wọn n pe ara wọn ni alaga ati kanselọ lẹyin ti ile ẹjọ ti yọ wọn.
'Iru igbesẹ bẹẹ jẹ titapa si ofin orileede wa ti ọdun 1999 ti wọn ti ṣatunṣe si. Bakan naa la tun n fidi rẹ mulẹ pe awọn darẹkitọ fun eto iṣuna ati ti akoso nikan ni wọn lẹtọọ labẹ ofin lati bu ọwọ lu sọwedowo to jẹ tijọba ibilẹ nibamu pẹlu abala kẹrinla akọsilẹ ilana iṣakoso ijọba ibilẹ l'Ọṣun.
'Ohun to n ṣẹlẹ nipinlẹ Ọṣun bayii jẹ ẹdun ọkan fun wa, a si n pe oluṣiro owo agba lorileede yii ati kọmiṣanna fun eto iṣuna lati tete yọnda owo to jẹ ti awọn ijọba ibilẹ l'Ọsun kiakia.''
Awọn aṣofin naa waa ṣeleri lati to ilana ofin lati fiya jẹ ẹnikẹni to ba ṣe lodi si awọn ipinnu wọn yii eleyii to wa labẹ ilana ofin lati daabo bo iṣejọba lẹsẹkuku.
No comments:
Post a Comment