Obinrin mẹta lo farapa nibi iṣẹlẹ ijamba ọkọ kan to ṣẹlẹ loni lorita Apomu loju-ọna Gbọngan nipinlẹ Ọṣun.
Agbẹnusọ fun ajọ ẹṣọ ojuupopo, Agnes Ogungbemi, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mẹta ọsan ku iṣẹju mẹẹdogun ni taya ọkọ Toyota Corolla alawọ dudu naa dede fọ lori ere.
O ni lasiko ti ojo n rọ lọwọ ni mọto to ni nọmba KRD 663 GT naa gbokiti lẹyin ti taya rẹ fọ.
Ogungbemi sọ siwaju pe ọkunrin meji ati obinrin mẹrin lo wa ninu ọkọ naa, ṣugbọn awọn mẹta ni wọn farapa.
O ni awọn ti ko awọn mẹtẹẹta lọ sileewosan Dove niluu Ikire fun itọju, ti wọn si ti gbe mọto ọhun kuro nibi to gbokiti si.
No comments:
Post a Comment