IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 19 June 2025

Osun 2026: Ibẹru ijakulẹ to n duro de ẹgbẹ APC lo fa a ti wọn fi n da wahala silẹ - Bunmi Jẹnyọ


Kọmiṣanna fun ọrọ okoowo ati ileeṣẹ nipinlẹ Ọṣun, Rev. Bunmi Jẹnyọ, ti sọ pe aimurasilẹ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress fun idibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun 2026 lo fa a ti wọn ṣe n da wahala silẹ lori ọrọ kansu bayii.


Jẹnyọ ni ko si ibi ti ijọba ọtọọtọ ti wa nipinlẹ ati ibilẹ ri, ṣe ni ẹgbẹ APC si mọ-ọn-mọ sọ ara wọn ni dagboru ni kansu pẹlu erongba pe awọn le di Gomina Ademọla Adeleke lọwọ ninu oniruuru iṣẹ rere to n ṣe kaakiri ipinlẹ Ọṣun.


O ni iyalẹnu lo jẹ pe awọn ti ile ẹjọ ti yọ kuro gẹgẹ bii alaga kansu tun le maa lọ kaakiri bayii pe awọn lawọn wa nijọba.


Nigba to n dahun ibeere awọn aṣojukọroyin lọjọ Tọsidee ọsẹ yii lo sọ pe, pẹlu nnkan to wa nilẹ bayii, ti idibo gomina ba waye loni l'Ọṣun, Adeleke yoo ko ibo ida aadọrin ninu ọgọrun, awọn ẹgbẹ oṣelu to ku yoo si maa pin ida ọgbọn to ṣẹku.


Jẹnyọ ṣalaye pe ohun ti ko ba dun mọ oun ninu ni kijọba yii ṣe atunṣe Cocoa Processing Industry to wa niluu Ẹdẹ, ko si bẹrẹ sii ṣiṣẹ, ṣugbọn ohun ti awọn ba nibẹ lọdun 2022 jẹ ibanujẹ ọkan.


O ni ijọba to kọja ti kọwe bọwe adehun ọlọdun marundinlogoji pẹlu awọn ara China lori ileeṣẹ naa, ṣugbọn nigba ti awọn araalu kofiri pe ibẹ nijọba yẹn ko palietiifu pamọ si, wọn ya lọ sibẹ, wọn si ba ibẹ jẹ kọjaa sisọ pẹlu awọn irinṣẹ olowo iyebiye to wa nibẹ.


Jẹnyọ sọ siwaju pe ijọba to kọja ko gbe igbesẹ kankan lori iṣẹlẹ yii, awọn ara China si ti n gbero lati gbe ipinlẹ Ọṣun lọ si kootu ko too di pe ijọba Adeleke de, ti oun, gẹgẹ bii kọmiṣanna, si ba awọn eeyan naa sọrọ ti wọn fi fori jin ijọba.


Lori awọn oniruuru iṣẹ akanṣe tawọn ijọba to ti kọja dawọ le, o ni ko si eyi tijọba Adeleke ko nii pari nitori owo ipinlẹ Ọṣun ni wọn fi bẹrẹ wọn, ko si nii si iṣẹ aṣepati kankan lasiko iṣejọba to wa lode.


Jẹnyọ waa ke si awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lati jẹ ki ijọba Adeleke sinmi, ki wọn jẹ ki alaafia wa nitori manigbagbe niṣejọba yii yoo jẹ ninu itan ipinlẹ Ọṣun lẹyin ọdun mẹjọ rẹ.

No comments:

Post a Comment