IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 26 June 2025

Eyi lohun to ṣẹlẹ laarin emi atawọn Amọtẹkun Ọṣun - Taiwo Ọlaọrẹ


Ọkan lara awọn abẹṣinkawọ Alhaji Gboyega Oyetọla to jẹ gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Taiwo Ọlaọrẹ, ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ laarin rẹ atawọn ajọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun.


Gẹgẹ bi Taiwo ṣe ṣalaye fawọn oniroyin niluu Oṣogbo, o ni, 'Ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ kọja iṣeju mẹwaa ọjọ Wẹsidee lawọn eeyan kan dede n tan tọọṣi kaakiri agbegbe ile mi niluu Iragbiji, bi ọkan lara wọn ṣe ri mi lo beere pe ṣe emi ni Taiwo, mo si beere pe ki lo ṣẹlẹ, ṣugbọn epe lo fi da mi lohun, to n beere pe ṣe n ko ya were.


'Ori eyi la wa ti awọn yooku rẹ fi wọle pẹlu ada ati ibọn lọwọ wọn. Iyawo mi ati ọmọ bẹrẹ sii sunkun pe nibo ni wọn ti wa nitori wọn ko wọ aṣọ idanimọ kankan, igba yẹn ni ọkan lara wọn sọ pe Amọtẹkun lawọn.


'Ọkada mẹta lawọn meje gbe wa, wọn si gbe mi si ori ọkan lara awọn ọkada yẹn pẹlu ankọọbu lọwọ, a gbera niluu Iragbiji, a si lo bii ọgbọn iṣẹju ko too di pe a de ọfiisi wọn ni Powerline niluu Oṣogbo nitori epo tan ninu ọkada ti wọn fi gbe mi, ṣe ni wọn ni lati fa epo ninu awọn ọkada to ku sinuu rẹ.


'Pẹlu igbaju-igbamu, wọn ju mi sinu atimọle wọn, mo si ba awọn bii mẹrin nibẹ. Lẹyin bii wakati meji, mo bẹrẹ sii gbọ iro ibọn nita, lẹyin ọrẹyin ni mo gbọ pe awọn eeyan mi ti wọn wa wo mi nibẹ lawọn Amọtẹkun tun doju kọ.


'Nigba to ya, wọn mu mi lọ sọdọ ọga wọn, Adekunle Ọmọyẹle lagbegbe Islahudeen ni Oke-Oniti, o beere lọwọ mi pe ṣe emi ni mo wa ninu fidio ti wọn ti sọ pe Amọtẹkun gba #6,700 sinu akanti Opay ẹnikan, mo si sọ pe rara.


'Lẹyin eyi ni wọn gbe mi lọ si olu ileeṣẹ awọn ọlọpaa niluu Oṣogbo, wọn si ja mi ju si ẹnu geeti. Nigba ti mo de ọdọ awọn ọlọpaa, ọlọpaa ti mo ba nibẹ sọ pe ki n maa lọ sile ati pe ki n pada wa laarọ oni Tọsidee, wi pe awọn yoo ranṣẹ si awọn Amọtẹkun naa lati wa.


'Laarọ oni, mo wa nibẹ fun ọpọ wakati, wọn gba ọrọ ẹnu mi silẹ, ṣugbọn awọn amọtẹkun ko yọju titi ti mo fi kuro nibẹ.


'N ko mọ nnkan ti mo ṣe ti wọn fi waa mu mi. Idajọ ododo ni mo n fẹ lori ọrọ yii. Mo si fẹ ki awọn ẹṣọ alaabo daabo bo emi ati idile mi nitori inu ibẹrubojo la wa bayii'

No comments:

Post a Comment