Alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, nipinlẹ Ọṣun, Hon. Sunday Bisi, ti sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun oun bi aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Oriade ati Obokun l'Abuja, Hon. Wọle Ọkẹ ṣe sọ ara rẹ di ẹyẹ ibaka lori ikanni ayelujara latigba to ti kuro ninu ẹgbẹ PDP.
Bisi sọ pe gbogbo igba ti oun ba ti ri oniruuru nnkan ti Ọkẹ n kọ loun maa n ri i bii ẹni a gboju okun le ṣugbọn ti ko jọ ẹni agba.
Nibi eto kan ti awọn oniroyin to ti fẹyinti nipinlẹ Ọṣun ṣagbekalẹ rẹ niluu Oṣogbo laipẹ yii ni Bisi ti ṣapejuwe Ọkẹ bii ọkanjua, ẹni to mọ tara rẹ nikan, ti ko si ni itẹlọrun.
O ni bawo ni aṣofin to ti lo ọdun mẹrinlelogun l'Abuja yoo ṣe maa binu si gomina to ṣẹṣẹ lo ọdun meji pere pe ko ṣe nnkan kan fawọn eeyan oun.
Gẹgẹ bo ṣe wi, 'Emi ri iwa ti aburo mi, Wọle Ọkẹ, hu gẹgẹ bii iwa ọkanjua, onimọtaraẹni nikan ati alainitẹlọrun. Ẹgbẹ to fun ọ lanfaani fun odidi ọdun mẹrinlelogun, o waa ro o pe ohun to yẹ ki o fi san oore fun iru ẹgbẹ bẹẹ ni ki o kuro nibẹ. Latigba to si ti lọ, ko si ọrọ gidi kankan ninu awijare to n sọ kaakiri, ṣugbọn a ti fi silẹ fun ẹri ọkan rẹ.
'Ki lo ṣe fun awọn eeyan rẹ lodidi ọdun mẹrinlelogun to ti lo nile igbimọ aṣofin apapọ l'Abuja? Nigeria Army Games Village to gbe wa si Ẹsa-oke, ki la ri nibẹ? O wa n sọ pe gomina to ṣẹṣẹ lo ọdun meji ko naani agbegbe oun, nitori idi eyi, o lọ sinu ẹgbẹ APC ti ko ranti agbegbe rẹ fodidi ọdun mejila ti wọn lo l'Ọṣun.
'Mo ti lọ si ẹkun idibo Ila lati ṣi iṣẹ akanṣe dida oju-ọna eleyii ti aṣofin to lọ siluu Abuja fungba akọkọ fẹẹ ṣe, ki ni Wọle Ọkẹ ṣe fawọn eeyan tiẹ? Awọn eeyan Oriade naa sọ pe awọn fẹẹ lọ, oun nikan kọ la da ile aye fun.
'Ọmọ to wa nileewe alakọbẹrẹ nigba ti iwọ ti bẹrẹ sii lọ sile igbimọ aṣofin sọ pe iyatọ gbọdọ ba iwẹ-aarọ ni Obokun ati Oriade, iwọ sọ pe rara. Ẹ fi silẹ, ọdun 2026 yoo fi iyatọ han laarin agbara-ojo ati omiyale. Ẹ jẹ ko lọ dan agbara wo ninu ẹgbẹ oṣelu miran, ko waa ri iye awọn to wa lẹyin rẹ.'
No comments:
Post a Comment