IROYIN YAJOYAJO

Monday, 23 June 2025

Olufẹ araalu ati alaanu mẹkunnu ni Oluwoo - Adewọle gboṣuba fun Ọba Akanbi


Minisita fun eto ilera nigba kan ri lorileede yii, Ọjọgbọn Isaac Fọlọrunṣọ Adewọle, ti ba Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdul-Rasheed Adewale Akanbi, dawọọdunnu ayẹyẹ orikadun ọdun kejidinlọgọta to de oke eepẹ.


Adewọle ṣapejuwe Oluwoo gẹgẹ bii ibunkun nla fun ilu Iwo ati iran Yoruba lapapọ nitori imọ kikun to ni ninu aṣa ti sọ ọ di aṣoju rere fun iran kaarọ-oojiire lorileede yii ati loke-okun.


O ni bi Ọba Akanbi ṣe jẹ ọlaju ti ran ilu naa lọwọ lọpọlọpọ ọna nitori oniruuru awọn iṣẹ idagbasoke lo ti ṣokunfa sibẹ lẹnu iwọnba ọdun to ti lo lori itẹ awọn babanla rẹ.


Adewọle sọ siwaju pe bi Oluwoo ṣe maa n digba fun awọn araalu rẹ lẹbun ṣafihan pe olufẹ araalu ati alaanu awọn mẹkunnu ni, idi si niyẹn ti awọn araalu rẹ fi maa n ṣugbaa rẹ nigba gbogbo.


O ni Ọba Akanbi fẹran ilu Iwo debii pe ko si nnkan kan ti ko le ṣe fun awọn eeyan rẹ lati le ri i pe ilu Iwo ko rẹyin laarin awọn ilu to ku niwọn igba to ba ti wa nibamu pẹlu ofin.


O ni iwa igboya ati ipinnu lati sọ ododo fun awọn alaṣẹ nibikibi to ba de tun ran ọba yii lọwọ lati tayọ laarin awọn ori-ade to ku.


Adewọle waa gbadura, lorukọ mọlẹbi rẹ, pe ki Ọlọrun tubọ maa dari Ọba Akanbi, ko si tubọ maa ri ojurere Olodumare nilẹ alaaye pẹlu alaafia.

No comments:

Post a Comment