IROYIN YAJOYAJO

Friday, 20 June 2025

Wahala n'Ido-Ayegunlẹ: Wọn pa eeyan mẹrin, wọn tun dana sun ọpọlọpọ dukia


Yatọ si eeyan meji ti wọn ṣi n wa bayii, eeyan mẹrin lo ti dero ọrun aremabọ latari wahala tuntun to bẹ silẹ ni ilu Ido-Ayegunlẹ nitosi Ẹsa-Oke nipinlẹ Ọṣun.


Gẹgẹ bi Ọbanla ilu naa, Ibironkẹ Adebusuyi, ṣe sọ, aago mẹwaa aarọ ọjọ Tọsidee to kọja lawọn janduku ti wọn sọ pe lati ilu Ẹsa Oke ni wọn ti wa ọhun ya wọ ilu Ido-Ayegunlẹ, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ.


Adebusuyi sọ pe awọn janduku ọhun to ọgọrun, ọkada ni wọn gun wọluu, bẹẹ ni wọn fi aṣọ bo oju wọn, ṣugbọn awọn araalu da awọn kan mọ laarin wọn.


Tẹ o ba gbagbe, latibẹrẹ ọdun yii ni wahala ti bẹrẹ nigba tijọba ipinlẹ Ọṣun fi Ọmọọba Oluwatimilẹyin Ajayi jẹ Olojudo ti Ido Ayegunlẹ. Awọn araalu naa fariga pe kp yẹ kijọba fi ẹni ti ki i ṣe ọmọ ilu awọn jọba, baalẹ to si wa nibẹ tẹlẹ lo yẹ kijọba sọ di ọba.


Ninu wahala tuntun yii, Adebusuyi sọ siwaju pe awọn janduku naa ge ori ọkunrin kan, wọn si ge ọwọ ẹnikan. O ni lẹyin ti wọn pa awọn eeyan mẹrẹẹrin ni wọn tun ju wọn sinuu kanga, ti wọn si gbe okuta nla le e lori.


Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Abiọdun Ọjẹlabi, sọ pe kọmiṣana ọlọpaa ti ṣabẹwo si ilu naa, wahala aala ilẹ to si ti wa laarin awọn ilu mejeeji tẹlẹ lo tun ṣokunfa iṣẹlẹ tuntun yii.

No comments:

Post a Comment