IROYIN YAJOYAJO

Friday, 13 June 2025

Osun 2026: Ti ẹgbẹ APC ba fa Babayẹmi kalẹ, irọrun lo ba de - Awọn ọdọ ijọba ibilẹ Ayedaade


Awọn ọdọ ti wọn le ni ẹgbẹrun meji kaakiri ijọba ibilẹ Ayedaade nipinlẹ Ọṣun ni wọn ti sọ pe ẹnikanṣoṣo to le mu ayipada ba ọrọ iṣejọba nipinlẹ Ọṣun ni Ọmọọba Dọtun Babayẹmi.


Lasiko ifikunlukun ti Babayẹmi, ọkan pataki lara awọn oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), n ṣe si ọdọ awọn adari ati lookọlookọ ninu ẹgbẹ naa nipa erongba rẹ, ni awọn ọdọ yii sọ pe irọrun ni yoo ba de bi ẹgbẹ APC ba le fa Babayẹmi kalẹ lọdun 2026.


Awọn ọdọ ti wọn wa lati gbogbo wọọdu to wa ni Ayedaade ọhun ṣeleri atilẹyin fun erongba Babayẹmi, wọn ni oun nikan lawọn nigbagbọ ninu iriri ati ọgbọn iṣakoso to ni lati le mu ki igbeaye rọrun fawọn araalu.


Nigba to n sọrọ lorukọ awọn ọdọ, Ọgbẹni Adekunle Rafiu ṣalaye idi ti wọn fi duro gbọn-in-gbọn-in pẹlu Babayẹmi, o ni o jẹ adari to ni afojusun rere, to si ni erongba lati sin araalu.


Adekunle ṣalaye pe ipa ti ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin lo ti ko nijọba ibilẹ Ayedaade ati nipinlẹ Ọṣun, niwọn igba to si rọ ọ lọrun lati maa ṣe nnkan meremere yii lai tii dipo oṣelu mu, o di dandan ko mu iyatọ ba iṣejọba to ba lanfaani lati di gomina.


O sọ siwaju pe Ọmọọba Dọtun Babayẹmi jẹ adari to ṣe e ṣawokọṣe lawujọ, oniruuru awọn nnkan to si la kalẹ pe oun fẹẹ ṣe duro lori idagbasoke ipinlẹ Ọṣun ati ipese iṣẹ fun awọn ọdọ.


Nitori naa, o ni awọn ọdọ ijọba ibilẹ naa ti fọwọ si erongba Babayẹmi lati gba tikẹẹti ẹgbẹ APC nipasẹ eyi ti yoo fi dije ninu idibo gomina ọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun 2026, bẹẹ ni wọn si rọ awọn adari ẹgbẹ naa lati ṣatilẹyin fun un nitori yoo rọrun fun ẹgbẹ wọn lati gbajọba lọwọ ẹgbẹ PDP ti wọn ba ti le fun Babayẹmi ni tikẹẹti.


Lẹyin eyi ni Babayẹmi dupẹ lọwọ awọn ọdọ atawọn agbaagba ẹgbẹ nijọba ibilẹ Ayedaade, o si sọ pẹlu idaniloju pe ipinlẹ Ọṣun yoo pada sọwọ ẹgbẹ APC lọdun to n bọ.

No comments:

Post a Comment