IROYIN YAJOYAJO

Monday, 30 June 2025

Wahala nbọ o! Adajọ agba l'Ọṣun fi ẹjọ kọmiṣanna feto idajọ sun ajọ to n fiya jẹ agbẹjọro to ba ṣiwahu


Wahala to n ṣẹlẹ lẹka eto idajọ nipinlẹ Ọṣun tun ti ba ọna miran yọ bayii pẹlu bi adajọ agba, Oyebọla Adepele Ojo, ṣe mu ẹjọ kọmiṣanna feto idajọ, Wọle Jimi-Bada lọ si ọdọ igbimọ to n fiya jẹ agbẹjọro to ba ṣe aṣemaṣe, iyẹn Legal Practitioners Disciplinary Committee (LPDC)


Adepele Ojo fẹsun kan Jimi-Bada pe o huwa lọna to lodi si ojuṣe rẹ, o si n ganu si ọrọ ti ko kan an.


Ninu iwe ẹsun to ni nọmba BB/LPDC/1672/2025, Ojo ṣalaye pe Jimi-Bada sọ ara rẹ di adele alaga igbimọ to n ri si ọrọ ẹka eto idajọ l'Ọṣun, Osun State Judicial Service Commission, ojuṣe to jẹ pe adajọ agba nikan lo le ṣe e.


Adepele Ojo sọ siwaju pe kọmiṣanna feto idajọ gbe lẹta kan jade ninu eyi to ti pe ipade, to si kede pe oun ti fọwọ si igbega awọn oṣiṣẹ kootu kan lai jẹ ki oun gbọ.


O ni iwa ti Bada hu yii lodi si ofin orileede Naijiria ti wọn mu atunṣe ba lọdun 1999, o si da rukerudo silẹ ni ẹka eto idajọ nipinlẹ Ọṣun.


Adepele fi kun ọrọ rẹ pe Jimi-Bada gbe awọn igbesẹ yii lọna to tako ẹjọ to wa niwaju kootu awọn oṣiṣẹ n'Ibadan lọwọlọwọ lori ọrọ awọn ajọ to n mojuto ọrọ ẹka eto idajọ nipinlẹ Ọṣun eleyii to nii ṣe pẹlu awọn ọmọ igbimọ ajọ naa to kọja.


O sọ siwaju pe iwa afojudi patapata si ẹka eto idajọ, ti ko si yẹ ka ba lọwọ agbẹjọro ni Jimi Bada hu.


Ninu idahun ajọ LPDC, wọn ti fi gbogbo awọn ẹsun naa to Jimi Bada leti, wọn si ni ko fi awijare rẹ ranṣẹ laarin ọjọ mérinlelogun. Wọn ni o gbọdọ fun akọwe ajọ naa ni ẹda esi mẹwaa ni ọfiisi wọn ni Abuja.

No comments:

Post a Comment