IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 2 July 2025

Njẹ ẹ ti gbọ? Arẹgbẹsọla ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu tuntun, koda, oun ni akọwe apapọ wọn


Minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii tẹlẹ, to tun jẹ gomina lẹẹmeji nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) bayii.


Ninu atẹjade kan ti alaga awọn ọmọlẹyin rẹ l'Ọṣun, Ọmọluabi Progressives, Alhaji Azeez Adesiji fi ki i ku oriire lo ti di mimọ pe Arẹgbẹṣọla ni akọwe apapọ ẹgbẹ naa lorileede yii.


O ke si awọn ọmọ ipinlẹ Ọṣun ti ko tii gba kaadi idibo lati tete lọ gba a nitori ẹgbẹ ADC yoo gbajọba lọwọ ẹgbẹ to n ṣejọba lọwọ bayii ninu idibo gomina ọdun 2026.


Ẹkunrẹrẹ nbọ laipẹ....

No comments:

Post a Comment