Igbimọ Agba ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọṣun ti fi da gbogbo araalu loju pe ko nii si ede-aiyede kankan lẹyin ti ẹgbẹ naa ba mu ẹni ti yoo jẹ ọmọ-oye wọn loṣu kọkanla ọdun yii.
Oṣu kọkanla ni ẹgbẹ oṣelu APC yoo ṣe idibo komẹsẹ-o-yọ fun gbogbo awọn to ba fi erongba wọn han lati dupo gomina, nipasẹ eyi ti wọn yoo yan ọmọ-oye ti yoo koju awọn oludije latinu ẹgbẹ oṣelu to ku lọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ ọsun 2026.
Nibi ipade kan ti igbimọ naa, labẹ alaga wọn, Ẹnjinia Ṣọla Akinwumi, ṣe pẹlu awọn to ti fi erongba wọn han lati du ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ APC, eleyii to waye niluu Ilobu, ni wọn ti ke si awọn oludije ọhun lati ṣe ara wọn lọkan, ki wọn si mọ pe bi eeyan marun ba n lepa ijoko kan ṣoṣo ẹni kan pere ni yoo ja mọ lọwọ.
Ẹnjinia Akinwumi ṣalaye pe awọn n mura awọn oludije ọhun silẹ ṣaaju idibo abẹle ni, o ni ki wọn ri ara wọn bii mọlẹbi kan, nitori ko nii si magomago kankan ninuu mimu ọmọ-oye ẹgbẹ naa.
O ni, lọwọlọwọ bayii, awọn to ti fi erongba han ti jẹ mọkanla, gbogbo wọn ni wọn si jẹ onisuuru, ko si onijagidijagan kankan laarin wọn, gbogbo wọn lawọn si ti ba sọrọ lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹnikẹni to ba jawe olubori ninu idibo abẹle loṣu kọkanla.
Lara awọn to n gbero lati di gomina ninu ẹgbẹ APC ti wọn wa nibi ipade ọhun ni Sẹnetọ Jide Ọmọworaarẹ, Dokita Akin Ogunbiyi, Ọmọọba Dọtun Babayẹmi ati Dokita Peter Babalọla
Awọn to ku ni Hon. Mudashiru Hussein, Alhaji Bọla Oyebamiji ati Agbẹjọro Agba Kunle Adegoke.
No comments:
Post a Comment