Ọfiisi iroyin fun aafin Ogunṣua ilu Mọdakẹkẹ nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ ti ẹnikan to pe ara rẹ ni Ọba Adeyinka Adeshina Ọbawale, Oluọjẹ ti Ọjẹnpetu n sọ kaakiri pe Ogunṣua ilu Mọdakẹkẹ, Ọba Joseph Olu Toriọla, Ajibise Ogo 1, ṣekọlu si oun.
Ọbawale la gbọ pe o ni Ogunṣua atawọn agbaagba kan niluu Mọdakẹkẹ n lepa ẹmi oun, ti wọn si ba dukia oun jẹ.
Ẹni to gbẹnusọ fun wọn, Oloye Kọla Ọlabisi, ṣalaye pe 'A fẹẹ sọ pẹlu idaniloju pe irọ patapata ni ẹsun ti ọkunrin kan to wa lati Gadumọ nipinlẹ Kogi, ṣugbọn to n pe ara rẹ ni ọba bayii, n pa pe Ogunṣua n lepa ẹmi oun, ṣe lo kan fẹẹ ba orukọ ati iyi ọba wa jẹ ni.
'Ọmọwe, ọlọpọlọ pipe, to si ni iriri pe iwa ọdaran ni lati ṣedajọ lọwọ ara ẹni, ni Kabiesi Toriọla. Ko yẹ ka fun Ọbawale lesi, ṣugbọn a ni lati sọrọ soke ko too di pe awọn eeyan ti ko lanfaani si otitọ gba irọ to n pa gbọ.
'Ojuṣe awọn agbofinro ni lati ri i pe awọn araalu pa ofin ati ilana mọ. O ya wa lẹnu bi Ọbawale ṣe n di ẹbi itaporogan to ni pẹlu awọn ọlọpaa le Ogunṣua atawọn ọmọ ilu lori.
'A fẹ ki ọkunrin to n pe ara rẹ ni Oluọjẹ ti Ọjẹnpetu yii tete mọ pe oun ko le ba ọba wa ati ilu wa lorukọ jẹ nipasẹ awọn to gbeṣẹ ran an. Ahesọ to n sọ kaakiri pe ọba wa korira awọn Fulani jẹ irọ lasan, gbogbo aye lo mọ pe ilu to gba onile-gbalejo ni Mọdakẹkẹ.
'Ohun ti a korira ni awọn ọta alaafia, a ko si nii beṣu-bẹgba lati fa wọn le awọn agbofinro lọwọ, ki iyatọ le wa laarin awọn adaluru atawọn olufẹ alaafia.
'Ti ẹnikẹni ba ro pe ọba wa yoo kawọ gbera, ti awọn agbesunmọmi, awọn ajinigbe, awọn adigunjale ati bẹẹ bẹẹ lọ, yoo gbakoso ilu, iru ẹni bẹẹ ṣe aṣiṣe nla.
'Ọba wa atawọn agbaagba ilu ko nii kaarẹ lati jẹ ki alaafia ati eto aabo to peye wa ninu ilu lati kin ijọba ibilẹ, ipinlẹ ati ijọba apapọ lọwọ ki alaafia pipe le wa lorileede yii.
'Kabiesi ti bẹ awọn agbẹjọro wọn lọwẹ lati gbe igbesẹ lori ẹni to ni afojusun lati ba a lorukọ jẹ. A wa n ke si ọga agba patapata funleeṣẹ ọlọpaa, alakoso agba fun ajọ DSS ati oludamọran pataki fun orileede yii lori eto aabo, lati gbe igbesẹ lori ọrọ yii kiakia.'
No comments:
Post a Comment