IROYIN YAJOYAJO

Friday, 25 July 2025

Eto idije Imọlẹ Millionaires yoo pese iṣẹ fun ẹgbẹrun mẹwaa ọdọ l'Ọṣun - Adebayọ


Oludasilẹ ileeṣẹ 2AG Integrated and Tailored Solutions Limited, Amofin Ladi Adebayọ, ti sọ pe, o kere tan, awọn ọdọ to to ẹgbẹrun mẹwaa ni yoo di oniṣẹ lọwọ nipasẹ eto Imọlẹ Millionaires Lottery ti ileeṣẹ oun, pẹju ajọṣepọ ijọba ipinlẹ Ọṣun, gbe kalẹ bayii.


Eto idije oriire Imọlẹ Millionaires ni Adebayọ sọ pe yoo mu adinku ba iṣẹ ati oṣi nipinlẹ Ọṣun, ti yoo si tun mu ki owo to n wọle funjọba labẹnu rugọgọ si i.


Lasiko to n mu awọn oniroyin kaakiri ibi ti wọn fẹ maa lo gẹgẹ bii olu ileeṣẹ naa, eleyii to wa lagbegbe Ita-Akọgun niluu Ileṣa, ni Adebayọ, ṣalaye pe oun pinnu lati gbe anfaani naa wa sipinlẹ Ọṣun lẹyin ti oun ti ṣaṣeyọri lori iru eto bẹẹ loke-okun.


Ọmọbibi ilu Iperindo nipinlẹ Ọṣun ọhun, to tun ti figba kan ri jẹ oludamọran pataki funjọba Ọṣun labẹ Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ṣalaye pe eto naa ko ni i ṣe pẹlu ọrọ oṣelu rara, bi ko ṣe lati mu aye rọrun fun awọn araalu.


O sọ siwaju pe kaakiri ipinlẹ Ọṣun lawọn yoo gba awọn oṣiṣẹ ti yoo maa lọ kaakiri lati la awọn araalu lọyẹ nipa eto naa, bẹẹ si ni wọn yoo ni ọpọlọpọ awọn aṣoju ti awọn araalu yoo maa ri tikẹẹti lọwọ wọn.


O ni nigba ti eto naa ba bẹrẹ logunjọ oṣu kẹsan ọdun yii, ẹẹdẹgbẹta naira lawọn araalu yoo fi maa ra tikẹẹti lati aago mẹsan alẹ ọjọ Satide, ti tikẹẹti tita yoo si wa sopin lọjọọ Satide to tẹle e.



Lẹyin eyi ni iyikoto oriire yoo maa waye laago meje alẹ gbogbo ọjọ Satide, ti gbogbo agbaye yoo si lanfaani lati wo o lorii gbogbo ikanni ayelujara. Oloriire akọkọ yoo gba miliọnu kan naira, ẹnikeji yoo gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira, nigba ti ẹnikẹta yoo janfaani ẹgbẹrun lọna ọtalelugba o din mẹwaa naira.


Oloriire kẹrin yoo lẹtọ si ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira, nigba ti ọkọọkan awọn eeyan aadọta to ba tẹle e yoo janfaani ẹgbẹrun lọna aadọta naira.


Adebayọ sọ siwaju pe ẹni to ba ti pe ọdun mejidinlogun soke nikan lo lanfaani lati ra tikẹẹti, bẹẹ ni awọn ẹrọ ti awọn yoo maa lo lagbara lati yọ ẹnikẹni to ba ti sọ rira tikẹẹti di baraku danu.


Awọn to ba fẹẹ ra tikẹẹti Imọlẹ Millionaires, gẹgẹ bi Adebayọ ṣe wi, le ra a nipasẹ awọn alagbata wọn ti yoo wa kaakiri ipinlẹ Ọṣun, wọn si le lo USSD ati APP.

No comments:

Post a Comment