IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 31 July 2025

A gbọdọ ṣiṣẹ papọ fun aṣeyọri idibo ọdun 2026 - Igbimọ Agba Ọṣun sọ fawọn ọmọ ẹgbẹ APC


Igbimọ Agba ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọṣun ti kede igbimọ ẹlẹni-mẹta ti yoo ri si aṣeyọri gbogbo idibo to n bọ lọna, bẹrẹ lati oṣu kẹjọ ọdun 2026.


Ọjọgbọn Isaac Adewọle ni yoo ṣe alaga igbimọ ọhun, nigba ti Hon. Jẹlili Adeṣiyan ati Hon. Isreal Famurewa yoo jẹ ọmọ igbimọ.


Ninu atẹjade ti alaga Igbimọ Agba Ọṣun, Ẹnjjinia Ṣọla Akinwumi, fọwọ si, léyin ipade to waye niluu Ilobu lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu keje ọdun yii ni wọn ti gboṣuba fun ọgbọn-inu ti Aarẹ Bọla Tinubu fi n tu ọkọ oṣelu orileede yii lai fi ti oniruuru ipenija ṣe.


Wọn  ke si gbogbo igun to wa labẹ ẹgbẹ naa lati ṣiṣẹ papọ, ki ẹgbẹ naa le ṣaṣeyọri ninu idibo gomina ọjọ kẹjọ oṣu kẹjọ ọdun 2026.


Bakan naa ni wọn sọ pe gbogbo awọn to n gbero lati du tikẹẹti ẹgbẹ naa fun ipo gomina gbọdọ wa niṣọkan gẹgé bi wọn ṣe ṣeleri laipẹ yii nitori idibo gomina ọdun 2026 ṣe pataki pupọ.


Igbimọ Agba ran gbogbo ọmọ ẹgbẹ leti lati la awọn araalu ti wọn ti to ọdun mejidinlogun lọyẹ lorii gbigba kaadi idibo nitori ohun kan ṣoṣo ti wọn fi le le ẹgbẹ PDP kuro lori aleefa niyẹn.


Wọn gboṣuba fun awọn to ṣẹṣẹ darapọ mọ ẹgbẹ APC latinu ẹgbẹ PDP, bẹẹ ni wọn lu minisita fun ọrọ okoowo ori-omi, Alhaji Isiaka Gboyega Oyetọla lọgọ ẹnu fun aduroti rẹ fun ẹgbẹ ni gbogbo igba.

No comments:

Post a Comment