Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti gboriyin fun ọga agba ileeṣẹ aṣọbode lorileede yii, Adewale Adeniyi, fun bo ṣe n gbogun ti aisi eto aabo to peye ni awọn aala ilẹ wa, ti owo to si n wọle si asunwọn ijọba fi n gbẹnu soke sii bayii.
Ọba Akanbi sọ pe Adeniyi lo iriri akọṣẹmọṣẹ to jẹ ati ọgbọn imọ-ẹrọ to ni lati fi ṣakoso awọn aala ilẹ wa, eyi si ṣeranwọ pupọ lati din ṣiṣe fayawọ ati pipolukumuṣu eto ọrọ-aje ku.
Ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin fun Oluwoo, Alli Ibraheem, fi sita lo ti sọ siwaju pe wahala nla ni bi ko ṣe si amojuto to peye ni awọn aala orileede yii tẹlẹ n ko ba ọrọ eto-aabo, ṣugbọn gbogbo eleyii ni opin de ba lasiko Adeniyi.
O ni Adeniyi ti fi ara rẹ han gẹgẹ bii adari rere, ẹni to ni ikora-ẹni nijanu, ẹni to ni iriri pupọ, ti iṣọwọṣiṣẹ ni awọn aala si ye e pupọ.
Oluwoo fi kun ọrọ rẹ pe owo ti ajọ naa n pa wọle labẹnu si asunwọn orileede yii bayii kọjaa keremi, o si fun ijọba apapọ lanfaani lati tubọ ri owo ṣe awọn nnkan ti yoo ṣe araalu lanfaani.
O lu Adeniyi lọgọ ẹnu lori iyansipo rẹ gẹgẹ bii alaga World Customs Organisation, eyi to ni o fihan pe ẹni tawọn eeyan mọriri rẹ lorileede yii ati ni gbogbo agbaye ni ọkunrin ọmọbibi ilu Mọdakẹkẹ ọhun jẹ.
No comments:
Post a Comment