IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 2 August 2025

2027: Mẹtala Atiku ati Obi ko le da Tinubu duro - Oloye Abiọla Ogundokun


Ọkan pataki lara awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ọṣun, Oloye Agba Abiọla Ogundokun, ti sọ pe alumọlẹ ni Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu yoo lu gbogbo awọn oludije ẹgbẹ oṣelu to ba dide tako o ninu idibo apapọ ọdun 2027.


Ogundokun, ẹni to jẹ Baṣọrun Musulumi funjọba ibilẹ Ayedire, Iwo ati ỌlaOluwa, ṣalaye pe ko si eyi to ni afojusun rere tabi iṣọkan lati pe Tinubu nija laarin ẹgbẹ PDP, Labour Party ati ADC.


O sọ ninu atẹjade kan laipẹ yii pe oloṣelu to gbọn ṣaṣa ni Aarẹ Tinubu, o si ti pẹ to ti n mura silẹ fun iṣejọba gẹgẹ bii aarẹ orileede yii.


Gẹgẹ bi Ogundokun ṣe wi, 'Aarẹ Tinubu ti rin jinna pupọ ṣaaju awọn alatako rẹ. Igbesẹ rẹ kan, iṣẹgun kan ni. Ẹ wo bi awọn oloṣelu nlanla ṣe n darapọ mọ ẹgbẹ APC bayii, ẹni ti oṣelu ye pupọ ni Tinubu.


'Ṣe lo yẹ ki ẹni to ba ni i lero pe oun fẹẹ ṣe aarẹ orileede yii bẹrẹ si i lọ ba Tinubu ṣepade, ko maa kọ ẹkọ lọdọ rẹ, ki i ṣe ko maa sare lati le e lori aga. Oloṣelu to ba pinnu lati dije lọdun 2027 lẹtọọ si i, ṣugbọn bii ẹni lọta ni Tinubu yoo lu gbogbo wọn mọlẹ'


Ogundokun fi kun ọrọ rẹ pe ẹni to yẹ ki wọn maa kọ ẹkọ nipa imọ oṣelu rẹ ni Fasiti ni Tinubu; o ni suuru, o gbọn ninu gbọn lode, o lorukọ rere, ko si ti i si aarẹ kankan ninu itan Naijiria to mura fun iṣejọba bii tirẹ.


O ke si igbakeji aarẹ orileede yii nigba kan, Alhaji Atiku Abubakar ati gomina ipinlẹ Anambra nigba kan ri, Peter Obi lati maṣe fi owo wọn ṣofo lọdun 2027 nitori ko le ṣee ṣe fun wọn lati da Tinubu duro.

No comments:

Post a Comment