Adajọ ile ẹjọ giga kan niluu Oṣogbo ti ju awọn ọkunrin mẹfa ti ọwọ tẹ lasiko idibo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun to waye lọdun 2023 si ẹwọn ọdun meji.
Awọn eeyan ọhun ni Yinusa Rahmon, Moshood Hamzat, Awotunde Gbenga, Adebayọ Mutiu, Fẹmi Taiwo ati Najeem Ọmọtuntun.
Ijọba apapọ lo wọ awọn mẹfẹẹfa lọ si kootu lori ẹsun pe wọn gbimọ pọ huwa buburu, wọn ni awọn nnkan ija oloro lọwọ lai gba aṣẹ ati iwa to le da omi alaafia agbegbe ru.
Inu otẹẹli kan niluu Ila lọwọ awọn ọmọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ ti tẹ awọn olujẹjọ yii lọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun 2023 lasiko ti idibo awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun n lọ lọwọ.
Onidajọ M. Awẹ ka ninu idajọ rẹ pe lara nnkan ti wọn ka mọ awọn olujẹjọ lọwọ lọjọ naa ni ibọn barẹẹli meji, ada meji, aake kan, ida fulani kan ati ọta-ibọn mẹfa.
Onidajọ yii sọ siwaju pe awọn olupẹjọ ko le fi idi ẹsun kẹta, iyẹn pe wọn huwa to le da omi alaafia agbegbe ru, mulẹ, nitori naa, ẹsun meji to ku lo dajọ le lori.
Lori ẹsun kinni, o ju ọkọọkan wọn si ẹwọn ọdun kọọkan tabi ki wọn san faini ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira. Lori ẹsun keji, o ju ọkọọkan wọn si ẹwọn ọdun meji tabi ki wọn san faini ẹgbẹrun lọna igba naira.
O ni ki wọn ka akoko ẹwọn naa tẹlera, bẹẹ ni ki wọn san faini naa papọ.
No comments:
Post a Comment