Olukọ kan ni Kogi State University, Anyigba, Dokita Ọlabọde Abimbọla Ibikunle la gbọ pe o gbẹmi mi lasiko ibalopọ pẹlu ọkan lara awọn akẹkọọbinrin fasiti naa to jẹ ẹya Ebira.
Otẹẹli la gbọ pe Ibikunle, ẹni ti wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii olukọ to buru ju lọ ni fasiti ọhun, mu akẹkọọ to wa nipele ọlọdun keji naa lọ lọjọ Wẹsidee ọsẹ yii.
Gbagedeọrọ gbọ pe oniruuru ọti amarale ni ọkunrin yii mu ki iṣẹ to bẹrẹ, o ti ṣe alakọkọ ti ko siyọnu, ẹlẹẹkeji lo fẹẹ ṣe ti nnkan fi yiwọ, to si gbabẹ sọda sọrun.
Akẹkọọbinrin yii pariwo, nigba ti awọn oṣiṣẹ otẹẹli yoo fi de, Ibikunle ti tutu. Loju ẹṣẹ naa ni wọn fa akẹkọọbinrin yii le awọn ọlọpaa lọwọ fun iwadi.
No comments:
Post a Comment