IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 16 July 2025

Idi ti mo fi kọwe fi ẹgbẹ PDP silẹ - Atiku Abubakar


Igbakeji aarẹ orileede yii nigba kan ri, Alhaji Atiku Abubakar, ti kọwe pe oun ko ṣe ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party mọ.


Ninu lẹta to kọ si alaga wọọdu rẹ nijọba ibilẹ Jada nipinlẹ Adamawa lọjọ kẹrinla oṣu keje ọdun yii lo ti ṣalaye pe oniruuru ede aiyede ti  ko ṣee pari to wa ninu ẹgbẹ naa bayii lo mu ki oun kuro.




Atiku, ẹni to ti dije fun ipo aarẹ orileede yii lẹẹmeji labẹ ẹgbẹ ọlọnburẹla sọ siwaju pe ọpọ nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa bayii lo tako afojusun awọn to da a silẹ.


O dupẹ lọwọ awọn adari ẹgbẹ fun anfaani ti wọn fun un lati ṣe igbakeji aarẹ fun saa meji, ati lati jẹ oludije funpo aarẹ lẹẹmeji ọtọọtọ, o si gbadura pe ki Ọlọrun wa pẹlu ẹgbẹ naa.

No comments:

Post a Comment