Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti sọ pe ibanujẹ nla ni iku Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Ọlakulẹhin jẹ fun gbogbo iran Yoruba.
Ninu ọrọ ibanikẹdun kan ti Adeleke fi sita nipasẹ agbẹnusọ rẹ, Mallam Rasheed Ọlawale, o ba gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinia Ṣeyi Makinde Olubadan in Council, idile Ọba Ọlakulẹhin atawọn ọmọ Ibadan kẹdun iku ọba nla to rewalẹ asa ọhun.
Idaji ọjọ Mọnde ọsẹ yii, iyẹn ọjọ keje oṣu keje ni Ọba Ọlakulẹhin waja lẹyin to lo aadọrun ọdun lori eepẹ, to si lo ọdun kan lori itẹ awọn babanla rẹ.
Gẹgẹ bi Adeleke ṣe sọ, asiko perete ti baba naa lo kun fun idagbasoke ti ko lẹgbẹ, ti iṣọkan si gbilẹ sii laarin awọn eeyan ilẹ Ibadan.
O ni ọba yii kun fun oore-ọfẹ, o si ni iwa ọmọluabi ti ori-ade fi maa n dari awọn eeyan rẹ, bẹẹ ni ko fi ifẹ to ni si awọn eeyan rẹ pamọ rara.
Adeleke sọ siwaju pe manigbagbe ni iwọnba asiko ti ọba yii lo gẹgẹ bii olubadan kẹtalelogoji, awọn iṣẹ rere to si fi silẹ yoo maa fọhun lẹyin rẹ.
O gbadura pe ki Ọlọrun tu awọn eeyan ilu Ibadan ninu, ko si tẹ baba naa safẹfẹ rere pẹlu awọn babanla rẹ.
No comments:
Post a Comment