IROYIN YAJOYAJO

Monday, 7 July 2025

Ajanaku sun bi oke! Olubadan, Ọba Ọlakulẹhin, waja


Lẹyin ọdun kan lori itẹ awọn babanla rẹ, Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Ọlakulẹhin, ti waja.


Idaji oni Mọnde, ọjọ keje oṣu keje ni baba ẹni aadọrun ọdun yii rewalẹ asa.


Ọjọ karun oṣu keje ọdun 1935 ni wọn bi baba yii, o si di Olubadan kẹtalelogoji lọjọ kejila oṣu keje ọdun 2024.

No comments:

Post a Comment