IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 8 July 2025

Awọn oloṣelu to korira idagbasoke orileede yii ni wọn ṣa ara wọn jọ sinu ADC - Ẹnjinia Ṣowade


Alakoso agba fun ajọ to n mojuto idagbasoke awọn agbegbe odo nipinlẹ Ogun ati Osun, iyẹn Ogun-Osun River Basin Development Authority, Ẹnjinia Olukayọde Ṣowade, ti sọ pe igba eṣinṣin awọn ẹgbẹ alatako ko to nnkan ti Aarẹ Bọla Tinubu yoo fi oṣuṣu ọwọ kanṣoṣo gbọn danu lọdun 2027.


Nibi eto kan to gbe kalẹ lati fi dẹrin pẹẹkẹ awọn eeyan ilu Ipetumodu nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ atawọn eeyan ilu Mọdakẹkẹ laipẹ yii lo ti ṣalaye pe awọn arijẹ nidii mọdaru, ti wọn fẹ ki orileede yii wa loju kan ni wọn ko ara wọn jọ sinu ẹgbẹ ADC bayii.


Ẹgbẹ African Democratic Party, ADC, ni awọn oloṣelu kan lorileede kede rẹ laipẹ yii pe awọn yoo lo lati fi yẹ aga mọ Tinubu nidi lọdun 2027. David Mark ni adele alaga wọn, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla si ni adele akọwe apapọ wọn.


Ṣugbọn Ṣowade sọ pe bawo ni agbarijọpọ awọn ẹgbẹ alatako to de, ti wọn ko tii rẹsẹ walẹ, ti wọn ti bẹrẹ sii ja si ipo laarin ara wọn, yoo ṣe sọ pe iyansipo saa keji Tinubu ko ni ṣee ṣe.


O sọ siwaju pe awọn oloṣelu kan naa ti wọn ti ba Aarẹ Tinubu jẹ, ti wọn si ti ba a mu, ṣugbọn ti wọn ko fẹ ki aarẹ mu ayipada rere wọ orileede yii ni wọn ṣa ara wọn kaakiri bayii, ti wọn ni awọn yoo dena de e lọdun 2027.


O ni ko si ẹka kankan ti Tinubu ko ti gbiyanju, gbogbo ẹni to ba si nifẹ orileede Naijiria yoo mọ pe ayipada daradara wa lasiko rẹ, o si yẹ ko tẹ siwaju lọdun 2027.


Ni ti eto iranwọ to n ṣe, eyi to pe orukọ rẹ ni Oyetọla Hands of Fellowship, o ni oun pinnu lati bẹrẹ eto naa, iru eyi toun ti ṣe lẹẹmarun-un ni Mọdakẹkẹ, niluu Ipetumodu ti i ṣe ilu abinibi iya to bi oun lati le jẹ ki erejẹ ijọba tiwantiwa tan kaakiri ipinlẹ Ọṣun.


O ni oun ṣawokọṣe gomina ana l'Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ẹni to maa n pin ounjẹ to pe ni Ounjẹ Ileri fun awọn araalu loṣooṣu nigba to wa nipo gomina, oun si mọ oniruuru ipa rere ti eto naa n ko ninu aye awọn araalu.


O ni bi oun ṣe bẹrẹ kaakiri awọn wọọdu nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ yii ko nii duro rara, bẹẹ ni eyi ti oun n ṣe niluu Mọdakẹkẹ n tẹ siwaju.


O ke si awọn eeyan nipinlẹ Ọṣun lati diboo wọn fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ninu idibo gomina ti yoo waye lọdun 2026 nitori ẹgbẹ naa nikan lo ni ifẹ wọn lọkan.


Gbogbo awọn ti wọn janfaani eto naa ni wọn gboriyin fun Ṣowade fun iranlọwọ oorekoore to n ṣe, wọn si ke si awọn oloṣelu to ku lati ṣawokọṣe rẹ.

No comments:

Post a Comment