Ti ki i ba ṣe ti awọn oṣiṣẹ ajọ Amọtẹkun ti wọn tete de si agbegbe Babasanya-Araka niluu Ẹdẹ nipinlẹ Ọṣun lọsan ọjọ Satide ọsẹ yii, awọn araalu i ba fi lilu da batani si ara ọkunrin Imaamu Agba kan nibẹ.
Imaamu Agba ti wọn pe orukọ rẹ ni Kadiri,to si to ọmọ ọgọta ọdun lọwọ tẹ lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹjọ to jẹ ọmọ alajọgbele rẹ lo pọ.
Nnkan bii aago mejila ọsan la gbọ pe iya ọmọdebinrin yii n wa a kaakiri, lojiji lo ti i nibi to ti n sunkun, ti ẹjẹ si n ṣan lara rẹ, to si sọ fun iya rẹ pe Imaamu Agba yii lo fipa ba oun lo pọ.
Wọn mu ọmọdebinrin yii lọ si Babasanya Hospital, nibẹ lawọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni baba agbalagba yii ti 'kinni' rẹ bọ abẹ ọmọdebinrin ọhun.
A gbọ pe ṣe ni wọn ti Imaamu Kadiri mọnuu yaara kan lọsibitu naa nigba tawọn araalu fẹẹ fiya to lọọrin jẹ ẹ, ko too di pe awọn kan sare ranṣẹ si awọn Amọtẹkun ti wọn gbe e kuro nibẹ, ti awọn yẹn si fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.
Ninu fidio kan ti Gbagedeọrọ ri, baba yii jẹwọ pe loootọ loun huwa naa, ṣugbọn o ṣeesi ni. O ni ẹpa loun ran ọmọdebinrin yii, bo si ṣe mu ẹpa de loun mu un wọnu yaara, ti oun si fipa ba a lo pọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l'Ọṣun, Abiọdun Ọjẹlabi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
No comments:
Post a Comment