IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 9 July 2025

Nitori ọrọ ilẹ, awọn ọmọ Oṣogbo fẹsun kan awọn ọmọọṣẹ Gomina Adeleke


Idile Oloogbe Sinatu Adeoye niluu Oṣogbo ti fẹsun kan awọn abẹṣinkawọ Gomina Ademọla Adeleke pe wọn n pagidina imuṣẹ idajọ ile-ẹjọ lori ọrọ ilẹ wọn to wa loju ọna Oṣogbo si Ikirun.


Ṣaaju ni Onidajọ R. O. Yusuf ti dajọ loṣu keji ọdun 1997 lori ẹjọ to ni nọmba HOS/71/1993 pe olujẹjọ, Hephzibar Holdings Ltd atawọn aṣoju rẹ ko gbọdọ wọnu ilẹ to jẹ ti Oloogbe Sinatu Adeoye mọ lailai.


Lẹyin ti awọn olujẹjọ kuna lati pe ẹjọ kotẹmilọrun ni awọn olupẹjọ tun gba kootu lọ loṣu keji ọdun 2025, Onidajọ A. O. Adebiyi si fun wọn lanfaani lati lọọ mu idajọ ile ẹjọ ṣẹ.


Ṣugbọn alubami lawọn ti wọn ti kọle, ti wọn si ti kọ ṣọọbu si ori ilẹ naa lu awọn oṣiṣẹ kootu, awọn amofin atawọn oniroyin loṣu karun ọdun yii nigba ti wọn lọ ṣami si awọn agbegbe to ti tasẹ agẹrẹ wọnu ilẹ naa.


Latigba naa, gẹgẹ bi awọn idile Adeoye ṣe sọ, lawọn olujẹjọ ti lọọ ko sabẹ awọn abẹnugan ninu ijọba Gomina Adeleke lati ri i daju pe wọn ko ṣe nnkan ti ile ẹjọ paṣẹ pe ki wọn ṣe.


A gbọ pe gbogbo ọna lawọn eeyan naa n gba lati ri i pe Amofin Lekan Alabi to n ṣoju idile Adeoye jawọ ninu ẹjọ ilẹ naa.


Koda, ijọba tun kọ iwe si ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun kọkanla lati da si i, ṣugbọn abọ iwadii igbimọ ti igbakeji ọga ọlọpaa patapata lorileede yii gbe kalẹ fi han pe ija ẹbi lawọn olujẹjọ n ja.


Awọn ọlọpaa gba wọn niyanju lati lọ yanju ọrọ naa nitubinnubi nitori idajọ ti awọn olupẹjọ mu dani ki i ṣe ayederu, kootu si ti fun wọn lagbara lati gbe igbesẹ lori ilẹ wọn.


Amọ ṣa, awọn mọlẹbi Adeoye ti ke si Gomina Adeleke lati kilọ fun awọn ọmọọṣẹ rẹ, paapaa, awọn ti wọn jẹ ọmọbibi ilu Oṣogbo, lati ganu kuro lori ọrọ idile awọn, ki wọn si gba idajọ ile ẹjọ laaye lati fẹsẹ mulẹ.

No comments:

Post a Comment