IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 24 July 2025

Kọmiṣanna feto idajọ l'Ọṣun, Wọle Jimi-Bada, di Agbẹjọro Agba lorileede yii


Igbimọ to n ri si ẹtọ awọn agbẹjọro lorileede yii, Legal Practitioners Privileges Committee, ti kede orukọ awọn agbẹjọro mẹtadinlọgọta ti wọn gba igbega si ipo Agbẹjọro Agba (SAN) bayii.


Lara wọn ni kọmiṣanna fun eto idajọ nipinlẹ Ọṣun, Oluwọle Tolulope Jimi-Bada  lati Ileefẹ ati Agbẹjọro Mubaraq Tijani Adekilekun lati ilu Ẹdẹ.


Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹsan ọdun yii la gbọ pe wọn yoo bura fun wọn.





 




No comments:

Post a Comment