IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 24 July 2025

Fadahunsi: Nnkan nla lo bọ sọnu lọwọ ẹgbẹ oṣelu PDP Ọṣun - IUGG


Ẹgbẹ kan to n ri si eto iṣejọba rere nilẹ Ijeṣa nipinlẹ Ọṣun, Ijesa Unite For Good Governance, ti sọ pe nnkan abamọ nla ni bi ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe kọ iha kokanmi titi ti sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan Ila-Oorun Ọṣun, Francis Adenigba Fadahunsi, ẹni to jẹ ọkan lara awọn ipilẹ ẹgbẹ naa, fi kuro laarin wọn.


IUGG, labẹ alaga apapọ wọn, Alhaji Kazeem Ibikunle, sọ pe adanu nla ni lilọ Fadahunsi jẹ fun ẹgbẹ PDP, paapaa nipinlẹ Ọṣun nitori akinkanju ti ọrọ oṣelu ye ni baba ọmọbibi ilu Ilaṣẹ-Ijeṣa ọhun.


Ninu atẹjade ti wọn fi sita ni ẹgbẹ naa ti sọ pe 'O ṣeni laanu pe ọkan pataki lara awọn to duro fun ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko to nira lati jẹ ọmọ ẹgbẹ alatako le lọ bẹyẹn.


''Adari to ni afojusun rere ni Sẹnetọ Fadahunsi, ko si sibi ti ọwọja oniruuru iṣẹ idagbasoke rẹ ko de. Lasiko ti Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla jẹ gomina, nnkan le pupọ, ṣugbọn Fadahunsi wa lara awọn to lo gbogbo agbara to ni lati ri i pe ẹgbẹ naa pada sijọba.


'Fadahunsi na owo ara rẹ lai duro de ẹnikẹni, lati le fa oju awọn araalu mọ ẹgbẹ PDP, abajade eleyii lo si han nigba ti Gomina Ademọla Adeleke fidi gomina to wa lori aleefa nigba naa janlẹ, ti ẹgbẹ PDP si ni aṣofin agba mẹta, aṣofin apapọ mẹsan ati ọmọ ile igbimọ aṣofin marundimlọgbọn ninuu mẹrindinlọgbọn.


'Ko sẹni to le ko iyan Fadahunsi kere rara ninu ẹgbẹ PDP, nigba ti oun nikan jẹ sẹnetọ nile igbimọ aṣofin agba, oniruuru nnkan lo ṣe fun ẹgbẹ. Yatọ si pe gbogbo ayẹyẹ ọdun ni yoo pin tirela irẹsi kaakiri, o ra bọọsi bọginni elero mẹrindinlaadọta fun ẹgbẹ.


'Bo ṣe n san owo ti wọn fi rẹnti sẹkiteriati, bẹẹ lo n sanwo awọn oṣiṣẹ ibẹ. O ra bọọsi elero mẹrindinlogun fun awọn oloye ẹgbẹ nipinlẹ, bẹẹ lo tun ra mọto fun awọn oloye ẹgbẹ ni ẹkun idibo rẹ ki iṣẹ iṣakoso le rọrun fun wọn pẹlu oniruuru nnkan ti ko ṣe e ka tan. 


'Oloṣelu to ṣe e ṣawokọse ni Fadahunsi, idi niyẹn to fi jẹ pe latigba to ti kọwe fi ẹgbẹ PDP silẹ lawọn oniruuru ẹgbẹ oṣelu ti n pe e pe ko wa darapọ mọ awọn nitori ẹni ti ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin to ba di ọrọ oṣelu ẹsẹkuku ni'


IUGG di ẹbi lilọ Fadahunsi ru aini-imọlara ilakọja awọn ọmọ ẹgbẹ ati kikọ etiikun si ikilọ eleyii ti wọn lo ti wọ awọn adari ẹgbẹ naa l'Ọṣun lẹwu. Wọn ni ti wọn ko ba tete wa nnkan ṣe si i, omi yoo tẹyin bọ igbin wọn lẹnu lọdun 2026.


Amọ ṣa, alaga ẹgbẹ oṣelu New Nigeria Peoples Party (NNPP) nipinlẹ Ọṣun, Dokita Tosin Ọdẹyẹmi, ti sọ pe gbagada nilẹkun ẹgbẹ naa ṣi silẹ fun Sẹnetọ Fadahunsi nitori wura iyebiye ni aṣofin ọhun, iroyin iṣẹ ribiribi to si ṣe nigba to wa ninu ẹgbẹ PDP fihan pe ẹni ti nnkan ye, to si mojuleja oṣelu ni.

No comments:

Post a Comment