Gomina ipinlẹ Rivers nigba kan ri, Rotimi Amaechi, ti kilọ fun awọn eeyan orileede Naijiria lati maṣe dibo fun Aarẹ Bọla Tinubu lẹẹkeji nibi idibo apapọ ti yoo waye lọdun 2027.
Amaechi ṣalaye pe bi inira ba le pọ to bayii lasiko iṣejọba saa akọkọ iṣejọba Tinubu, o daju pe pupọ ọmọ orileede yii ni ebi ọpagbafọwọmẹkẹ yoo ran sọrun aremabọ to ba le wọle fun saa keji.
Nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ African Democratic Congress, ADC, sọrọ nipinlẹ Rivers ni Amaechi sọ fun wọn pe afojusun ọdun 2027 ṣe pataki lati jajabọ lọwọ inira to n koju ọpọ idile bayii.
O ke si awọn eeyan ipinlẹ Rivers lati maṣe faaye gba awọn ti wọn ti maa n kọ esi idibo ṣaaju ọjọ idibo mọ nipinlẹ ọhun, o ni iru iwa bẹẹ maa n ko irẹwẹsi ba awọn oludibo ni.
Amaechi sọ siwaju pe ẹgbẹ naa yoo gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo maa lọ lati wọọdu de wọọdu lati la awọn araalu lọyẹ nipa iforukọsilẹ gẹgẹ bii oludibo.
No comments:
Post a Comment