IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 12 July 2025

Ibi ti o ba n lọ lawa naa n lọ, digbi la wa lẹyin rẹ - Awọn abẹṣinkawọ Adeleke fi i lọkan balẹ


Gbogbo awọn abẹṣinkawọ gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke, latijọba apapọ, titi de ijọba ibilẹ, ni wọn ti fi i lọkan balẹ pe ko ma bẹru, awọn wa pẹlu rẹ ninu gbogbo igbesẹ to ba fẹẹ gbe lori ahesọ to n lọ kaakiri bayii.


Ọpọ awọn eeyan ni wọn ti n sọ pe Adeleke n lọ sinu ẹgbẹ oṣelu APC ṣaaju idibo gomina ipinlẹ Ọṣun to n bọ lọdun 2026.


Nibi ipade kan to waye ninu ile ijọba niluu Oṣogbo lọsan ọjọ Satide ọsẹ yii ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin agba atawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ lati Ọṣun, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ọṣun, awọn kọmiṣanna, awọn oludamọran pataki atawọn oloye ALGON ti sọ pe ki Adeleke tẹsiwaju ninu ifikunlukun to n ṣe kaakiri bayii lori ẹgbẹ to fẹẹ lọ.


Wọn ni awọn nigbagbọ to daju ninu ọgbọn adari rẹ, idi niyẹn tawọn fi pinnu lati duro ti i nitori ko nii ṣi awọn dari.


Lara awọn ti wọn tun wa nibi ipade naa ni Yeye Dupẹ Adeleke, Kamọrudeen Ajiṣafẹ, Adewale Ẹgbẹdun, Sunday Bisi, Hon. Teslim Igbalaye, Hon. Kazeem Akinlẹyẹ, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla, Sen. Olu Alabi, Alh. Tajudeen Ọladipọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

No comments:

Post a Comment