IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 9 July 2025

Sunday Bisi di ọtẹlẹmuyẹ apapandodo, lọwọ-lẹsẹ lo n ṣọ awọn aṣofin PDP l'Abuja


Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Sunday Bisi, ti kilọ fun awọn aṣofin ẹgbẹ naa to wa l'Abuja lati kiyesara nipa gbogbo nnkan ti wọn ba n ṣe.


Bisi sọ pe oun ni awọn ti wọn n ṣọ awọn aṣofin yii lọwọ-lẹsẹ niluu Abuja, ojoojumọ ni wọn si n fun oun labọ irin ẹnikọọkan wọn.


Sẹnetọ mẹta atawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ mẹsan-an ni wọn n ṣojuu gbogbo ẹkun idibo to wa l'Ọṣun ni Abuja.


Nibi ipade kan tawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun ṣe laipẹ yii ni alaga yii ti fi aidunnu rẹ han si bi ọpọ awọn aṣofin naa ṣe n huwa l'Abuja eyi to ni wọn n ṣe bii ẹni pe wọn ko nii nilo ẹgbẹ mọ.


Gẹgẹ bo ṣe wi ninu fọnran fidio kan ti Gbagedeọrọ ri, 'Ẹyin lẹ dibo yan wọn lati lọ fun ipo sẹnetọ ati ile aṣojuṣofin kekere, ẹ ko sọ pe ki wọn lo ọdun meji ki wọn ta kọsọ sinu ẹgbẹ oṣelu miran o. Ẹni to ba n ṣeyẹn, o ti dalẹ niyẹn, ilẹ si maa da iru ẹni naa. Mo si mọ pe atubọtan wọn ko nii dara tori omije, ẹjẹ ara, ati gbogbo nnkan la fi ko ẹgbẹ yii jọ, ohun la fi ṣe idibo ti a fi wọle, ina ti a waa ko jọ, to n jo geee yẹn, ẹni to ba ni oun fẹẹ gbiyanju lati bomi pa a, Ọlọrun a bomi pa ina aye rẹ. 


'Ẹ ba wa ba wọn sọrọ tori ẹlomiin n ṣe bii ẹni ti ko nii pada sile mọ, ẹlomiin n ṣe bii ẹni ti ko nii nilo ẹgbẹ mọ, ọjọ lo n pẹ o, ipade ki i jinna, gbogbo bi onikaluku wọn ṣe n rin l'Abuja patapata la n gbọ lojoojumọ, mo ti gba ripọọtu ti aarọ yii, ti tana wa lọwọ mi, gbogbo bi wọn ṣe n rin la n mọ, ṣugbọn ẹ jẹ ki wọn forukọ rere silẹ, ẹ ba wọn sọrọ nibi ti wọn ti n gbọ, ẹ sọ fun wọn pe ojo a maa paayan wọle kan lẹẹmeji.


'Ẹ ba wa kilọ fun wọn, awọn naa bimọ, wọn si fẹẹ fi ọla silẹ fun ọmọ wọn.'


Tẹ o ba gbagbe, latigba ti aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Oriade ati Obokun nile igbimọ aṣofin apapọ, Hon. Wọle Ọkẹ, ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP bo sinuu APC ni awuyewuye ti bẹrẹ lori irinajo awọn aṣofin kan ti wọn n fura si pe o ṣee ṣe ki awọn naa ta kusọ kuro ninu ẹgbẹ naa laipẹ.

No comments:

Post a Comment