IROYIN YAJOYAJO

Monday, 14 July 2025

Nitori Buhari, ijọba apapọ kede ọlude


Nitẹsiwaju ọjọ meje tijọba apapọ kede lati fi ṣọfọ aarẹ ana lorileede yii, Mohammadu Buhari, wọn ti kede ọjọ Tusidee, ọjọ kẹẹdogun oṣu keje ọdun yii gẹgẹ bii ọlude fun awọn oṣiṣẹ.


Buhari lo dagbere faye lọjọ Sannde nileewosan kan to ti n gbatọju ni London. Ẹni ọdun mejilelọgọrin ni kọlọjọ too de, ọjọ Tusidee nireti si wa pe wọn yoo sinku rẹ ni Daura nipinlẹ Katsina.


Atẹjade kan latọwọ minisita fun ọrọ abẹle, Dokita Olubunmi Tunji-Ojo sọ pe ọlude naa wa lati bu ẹyẹ ikẹyin fun Buhari fun iṣẹ rere to ṣe lasiko to fi ṣe aarẹ orileede yii.


O ni Buhari sin orileede yii tọkantọkan ati otitọ inu, bẹẹ ni ko yẹsẹ ninu iṣọkan Naijiria. Ojo sọ siwaju pe adari rere to ko ipa manigbagbe ninu idagbasoke orileede yii ni aarẹ to doloogbe ọhun.


Ṣaaju nijọba apapọ ti kede pe fun odidi ọjọ meje ni asia orileede yii yoo fi wa ni tita laabọ lati bu ọla fun Buhari.

No comments:

Post a Comment