IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 19 July 2025

L'Ọṣun, Sẹnetọ Fadahunsi kọwe fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ


Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Ifẹ/Ijeṣa nile igbimọ aṣofin agba orileede yii, Senator Francis Adenigba Fadahunsi ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ bayii.

Ninu lẹta to kọ si alaga wọọdu rẹ nijọba ibilẹ Obokun lọjọ kejila oṣu kẹfa ọdun yii lo ti ṣalaye pe oun ti fikunlukun pẹlu awọn mọlẹbi atawọn ololufẹ oun ki oun too gbe igbesẹ naa.

Lara idi to ni o mu oun fi ẹgbẹ ọlọmburẹla silẹ ni wahala ojoojumọ, ede aiyede ti ko yanju bọrọbọrọ ati gbigbe ara ẹni lọ si kootu ojoojumọ.

No comments:

Post a Comment