Bo tilẹ jẹ pe awọn sẹnetọ ẹgbẹ oṣelu PDP meji latipinlẹ Ọṣun ti wọn kọwe fi ẹgbẹ silẹ laipẹ yii ko ti i kede ibi ti wọn n lọ, iwadii ti fi han bayii pe o ṣee ṣe ko jẹ inu ẹgbẹ APC ni wọn yoo sọ ẹru wọn ka.
Laipẹ yii ni sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan Ila-Oorun Ọsun, Francis Adenigba Fadahunsi ati ti Aaringbungbun Ọṣun, Oluwọle Fadeyi Ajagunnla, kọwe fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ latari oniruuru ede aiyede ti ko ṣee yanju ninu ẹgbẹ naa.
Amọ ṣa, iwadi Gbagedeọrọ fi han pe lati oṣu diẹ sẹyin lawọn sẹnetọ yii ti ṣepade pẹlu Aarẹ Bọla Tinubi, ti iyẹn si ti fi wọn lọkan balẹ pe anfaani wa fun wọn ninu ẹgbẹ APC.
A gbọ pe ṣaaju akoko naa lawọn abẹnugan kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP l'Ọṣun ti n dunkoko mọ awọn sẹnetọ yii pe wọn ko nii ri tikẹẹti ẹgbẹ gba fun idibo apapọ ọdun 2027.
Ṣugbọn ko pẹ rara ti ahesọ fi jade pe gomina funraarẹ, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti bẹrẹ igbesẹ lati digbadagbọn rẹ kuro ninu ẹgbẹ PDP lọ sinu ẹgbẹ APC, ti ahesọ naa si ti n dabii ẹni pe o fẹẹ ja si ootọ bayii.
Gbogbo awọn abẹṣinkawọ Adeleke atawọn agbaagba ẹgbẹ naa ni wọn ti ṣẹleri fun un pe ibikibi to ba n lọ lori ọrọ atunyansipo rẹ lọdun 2026 lawọn yoo tẹle e.
Tẹ o ba si gbagbe, aṣofin lati ẹkun idibo Oriade/Obokun, Hon Oluwọle Ọkẹ, lo kọkọ kuro ninu ẹgbẹ PDP loṣu mẹrin sẹyin, ti iyẹn si sọ pẹlu idaniloju nigba naa pe oun ko nii da rin, ọnburẹla yoo faya tan l'Ọṣun.
Gbogbo araalu ni wọn fọwọ lẹran bayii lati wo bi awọn ti wọn dipo oṣelu mu labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP l'Ọṣun ṣe n ju ọmburẹla silẹ, ti wọn si n ta mọ ọkọ ẹgbẹ APC.
Gbagedeọrọ gbọ pe gbogbo bi Gomina Ademọla Adeleke ati ẹgbọn rẹ, Dokita Deji Adeleke, ṣe n lọ kaakiri lati yanju ọrọ kikọja sinu ẹgbẹ APC ni wọn ko bun awọn aṣofin yii gbọ rara, ọrọ si ti di pe ṣe ni kaluku n ja fun ori ara rẹ bayii.
No comments:
Post a Comment