Ọkunrin agbẹ kan, Akeem Jimoh, ni wọn ti ba oku rẹ ninu oko to n da laarin ilu Ipetumodu si Aṣipa nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ nipinlẹ Ọṣun lọjọ Tọsidee to kọja.
Gẹgẹ bi awọn mọlẹbi ọkunrin yii ṣe sọ, aago meje aabọ arọ lo lọ sinu oko rẹ, ṣugbọn aago mejila ọsan niroyin tan kaakiri ilu Ipetumodu pe awọn kan ti pa ọkunrin naa sinu oko rẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa l'Ọṣun, Abiọdun Ọjẹlabi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ohun ti awọn ṣakiyesi ni pe ṣe ni wọn gun ọkunrin naa pa.
A gbọ pe ọrọ naa fẹẹ da wahala silẹ nitori ṣe lawọn ara ilu Ipetumodu yari kanlẹ pe awọn ko nii gba, ṣugbọn awọn ọlọpaa ti si ṣẹleri fun wọn pe awọn yoo tuṣu desalẹ ikoko iṣẹlẹ ọhun, bẹẹ ni ẹlẹṣẹ kan ki yoo lọ lai jiya.
No comments:
Post a Comment