IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 19 July 2025

Ọnburẹla ti fẹẹ faya tan l'Ọṣun o! Sẹnetọ Fadeyi Ajagunla kọwe fi ẹgbẹ PDP silẹ


Lẹyin wakati diẹ tiroyin jade pe sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan Ila Oorun Ọṣun nile igbimọ aṣofin apapọ l'Abuja, Francis Fadahunsi, ti kọwe fi ẹgbẹ PDP silẹ, Sẹnetọ Olubiyi Oluwọle Fadeyi naa ti sọ pe oun ko ṣe ẹgbẹ ọlọnburẹla mọ.

Ninu lẹta to kọ si alaga wọọdu rẹ ni Oke-Ejigbo, Ila Ọrangun, lọjọ kejila oṣu kẹfa ọdun yii ni aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Aaringbungbun Ọṣun l'Abuja ti sọ pe ede aiyede to ti pin ẹgbẹ naa yẹlẹyẹlẹ bayii lo fa a ti oun fi kọwe fi ẹgbẹ silẹ.

No comments:

Post a Comment