Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti fi da awọn araalu loju pe gbogbo ileri ti oun ṣe fun wọn loun yoo mu ṣe lai si iṣẹ aṣepati kankan.
Lasiko to n ṣe ifilọlẹ iṣẹ akanṣe oju-ọna alabalameji ninu ilu Ila-Ọrangun ati oju-ọna Oṣogbo si Ikirun titi de Ila-Odo lọjọ Mọnde ọsẹ yii ni Adeleke sọ pe afojusun oun ni lati ṣe amuṣẹ awọn adehun ẹlẹga marun-un ti oun ni pẹlu awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun.
Adeleke, ẹni ti ogunlọgọ awọn ara agbegbe to lọ ọhun tu jade lati ki kaabọ sọ pe ko si ilu ti ọwọja iṣẹ akanṣe ojuupopo ko tii de latigba ti oun ti de ori aleefa.
O ṣalaye fun wọn pe igba kilomita oju-ọna nijọba oun ti pari, bẹẹ ni iṣẹ n lọ lọwọ lojoojumọ ni awọn oju-ọna tijọba fẹẹ sọ di alabala meji atawọn afara abẹyẹfo.
Adeleke sọ siwaju pe sisọ oju ọna Ileṣa di alabala meji ti de ida mejidinlọgọrin ninu ida ọgọrun, afara abẹyẹfo ilu Ileeḟẹ ti de ida marundinlọgọrin, afara abẹyẹfo Okefia ti de ida marundinlọgọrun, nigba ti eyi to wa ni LAMECO ti de ida marunlelaadọta.
O ni ko fẹẹ si ijọba ibilẹ tijọba ko tii ṣe ọna onikilomita-kan ataabọ, bẹẹ ni afara Oke Gada ti pari.
Gomina fi kun ọrọ rẹ pe ijọba to ni ipinnu ọkan loun n ṣe, ko si si ohunkohun to le mu ki oun yẹsẹ ninu awọn adehun ti oun ṣe pẹlu awọn araalu nitori atilẹyin wọn lo jẹ okun fun iṣẹjọba oun.
No comments:
Post a Comment