IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 22 July 2025

Loootọ, o nira fun mi, ṣugbọn mo ni lati fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ - Hon. Taofeek Ajilesoro


Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Ifẹ nile igbimọ aṣofin apapọ orileede yii, Hon. Taofeek Abimbọla Ajileṣoro, ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ.


Ni bayii, o ti di sẹnetọ meji ati ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ meji lati ipinlẹ Ọṣun ti wọn kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.


Ninu lẹta ti Ajileṣoro kọ si alaga wọọdu idibo rẹ ni Ilarẹ Ward 11, nijọba ibilẹ Aaringbungbun Ifẹ lọjọ kejilelogun oṣu kéfa ọdun yii, lo ti sọ pe igbesẹ naa nira fun oun lati gbe.


O ni wahala ija ojoojumọ to ti fa ọpọlọpọ iyapa sinu ẹgbẹ oṣelu naa bayii lo fa a ti oun fi pinnu lati fi ọnburẹla silẹ.


O dupẹ lọwọ awọn adari ẹgbẹ fun anfaani ti wọn fun un lati sin awọn eeyan rẹ.

No comments:

Post a Comment