Ti aworan kan to n lọ kaakiri ikanni ayelujara bayii ba jẹ ootọ, a jẹ pe iwọ ẹgbẹ oṣelu APC l'Ọṣun tun ti gbe ẹja nla miran ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Honourable Olusanya Omirin to n ṣoju awọn eeyan Guusu Ijeṣa nile igbimọ aṣofin apapọ lo ya fọto pẹlu gomina ana l'Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla.
Pẹlu bo ṣe boyin kẹẹ ninu fọto naa, awọn lamẹẹtọ ilu sọ pe o ṣee ṣe ki ọrọ ti wọ laarin oun atawọn ẹgbẹ APC Ọṣun, ti yoo si kede lilọ rẹ laipẹ.
To ba waa jẹ bẹẹ, APC ti ja Sẹnetọ meji; Francis Adenigba Fadahunsi ati Olubiyi Ajagunla atawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ mẹta; Wọle Ọke, Taofeek Ajileṣoro ati Sanya Omirin gba mọ ẹgbẹ PDP Ọṣun lọwọ niyẹn.
No comments:
Post a Comment