Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti sọ pe abadofin to nii ṣe pẹlu ina mọnamọna ti awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ṣẹṣẹ buwọ lu yoo mu ki ayipada rere ba eto ọrọ-aje, ti ara yoo si tu awọn araalu.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina, Mallam Ọlawale Rasheed fọwọ si, lo ti di mimọ pe anfaani nla ni ofin naa jẹ fun awọn oludokoowo ni ẹka nnkan amuṣagbara pẹluu bi ibudo ipese ina-ọba lorileede yii ṣe n dẹnukọlẹ lojoojumọ.
O ni oniruuru ọna ni wọn yoo ti maa pese ina mọnamọna bayi, ti eleyii yoo si fopin si segeṣege to n waye ni ẹka naa kaakiri ipinlẹ Ọṣun.
O sọ siwaju pe ajọ yii yoo lagbara lati maa wojutu si itaporogan to maa n waye laarin awọn araalu atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n pin ina mọnamọna lagbegbe yii nitori ajọ naa yoo ri i pe ko si iyanjẹ ninu ina-ọba tawọn onibaara n lo ati owo ti ajọ to n pin ina n gba lọwọ wọn.
O gba ileeṣe to n pin ina ijọba nimọran lati gbaradi kiakia ko too di pe ofin naa yoo gberasọ loju mejeeji.
Gomina fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo awọn lookọ-lookọ ti ọrọ kan loun yoo ranṣẹ pe laipẹ yii fun bibuwọ lu ofin tuntun ọhun, eleyii ti yoo mu ki ara tu awọn olokoowo nipinlẹ Ọṣun.
O gboriyin fun awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin, ileeṣẹ ohun amuṣagbara atawọn ti wọn kopa ninu sisọ aba naa di ofin.
No comments:
Post a Comment