Nimurasilẹ fun idibo gomina ti yoo waye nipinlẹ Ọṣun loṣu kẹjọ ọdun 2026, akọwe apapọ fun ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti ṣabẹwo si gomina tẹlẹ ri l'Ọṣun, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla ni ile rẹ to wa niluu Okuku.
Irọlẹ ọjọ Sannde to kọja, iyẹn ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keje ọdun yii ni Arẹgbẹṣọla atawọn eeyan kan ninu ẹgbẹ ADC Ọṣun lọ sọdọ Oyinlọla.
Tẹ o ba gbagbe, Arẹgbẹṣọla ti ẹgbẹ APC lo bọ sori aleefa lẹyin ti ile ẹjọ fopin si iṣejọba Ọmọọba Oyinlọla ti ẹgbẹ PDP lọdun 2010. Lẹyin ọdun diẹ ti Oyinlọla darapọ mọ ẹgbẹ APC ni ibaṣepọ aarin awọn gomina mejeeji tun gun rege sii. Arẹgbẹṣọla maa n ṣabẹwo si Oyinlọla l'Okuku lẹẹkọọkan to ba lọ sipinlẹ Ọṣun lẹyin to kuro nipo gomina ko too di akọwe apapọ ẹgbẹ ADC bayii.
Gẹgẹ bi Gbagedeọrọ ṣe gbọ, nibi abẹwo naa ni Arẹgbẹṣọla ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ fun Oyinlọla, idi ti wọn fi darapọ mọ ẹgbẹ ADC lati ṣe ẹgbẹ oṣelu alasopọ ati awọn nnkan to jẹ afojusun ẹgbẹ naa.
Iwadii fi han pe pupọ awọn oloṣelu nlanla nipinlẹ Ọṣun, latinu ẹgbẹ PDP ati APC ni Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla yoo ṣe iru abẹwo yii kan naa si ṣaaju idibo gomina l'Ọṣun.
Amọ ṣa, Oyinlọla dupẹ lọwọ Arẹgbẹṣọla fun abẹwo rẹ, o si gbadura fun un pe yoo ṣaṣeyọri ninu ipo tuntun to ṣẹṣẹ gba ọhun nitori oun naa mọ awọn ipenija to wa nibẹ gẹgẹ bii akọwe apapọ nigba kan ri fun ẹgbẹ PDP.
No comments:
Post a Comment