IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 24 July 2025

Ọjọgbọn Yilwatda di alaga apapọ fun ẹgbẹ oṣelu APC


Minisita fun ọrọ igbayegbadun araalu, Ọjọgbọn Nentawe Yilwatda lo ti di alaga apapọ fun ẹgbẹ All Progressives Congress lorileede yii bayii.


Nibi ipade awọn ọmọ igbimọ alakoso ẹgbẹ naa to waye lọjọ Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun oṣu keje ọdun yii l'Abuja, ni wọn ti yan an.


Oun lo rọpo alaga wọn tẹle, Abdullahi Ganduje, ẹni to kọwe fi ipo rẹ silẹ loṣu to kọja lori awijare pe ilera oun ko gbe iṣẹ naa mọ.


Igbakeji alaga apapọ lati iha Ariwa, Ali Bukar Dalori, lo dele tẹlẹ ko too di pe wọn yan Yilwatda bayii.

No comments:

Post a Comment