IROYIN YAJOYAJO

Friday, 4 July 2025

Rara o! Mi o tu ẹgbẹ mi ka fun awọn Ọmọluabi Progressives, ṣe la gba wọn lalejo - Alaga ADC Ọṣun sọrọ soke


Alaga ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) nipinlẹ Ọṣun, Comrade Idowu Omidiji ti sọ pe ko si ootọ ninu iroyin kan to n lọ kaakiri pe oun ti tu ẹgbẹ oṣelu naa ka fun awọn Ọmọluabi Progressives.


ADC ni ẹgbẹ oṣelu ti awọn oloṣelu ti wọn fẹẹ yẹ Aarẹ Tinubu ni saa lọdun 2027 fẹẹ lo, wọn si ti kede minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii tẹlẹ, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, gẹgẹ bii akọwe apapọ wọn.


Awọn ọmọlẹyin Arẹgbẹṣọla ni wọn n jẹ Ọmọluabi Progressives nipinlẹ Ọṣun.


Latigba ti wọn si ti kede pe Arẹgbẹṣọla ni akọwe apapọ wọn ni iroyin ti n lọ kaakiri pe ẹgbẹ ADC nipinlẹ Ọṣun ti tu ile ka fun Ọmọluabi Progressives.


Ṣugbọn Omidiji sọ pe ko si ootọ ninu iroyin naa. O ni ko ṣee ṣe fun onile lati tu ile ka tabi yọnda ohun to ti tu jọ sinu ile rẹ fun ẹni to wa ba a.

Nigba to n ba Gbagedeọrọ sọrọ lorii foonu lọjọ Furaidee ọsẹ yii, o ni, ''A ko tu ẹgbẹ ka, a jọ fẹẹ ṣiṣẹ papọ ni, awọn ni wọn wa ba wa, a ko tu agbekalẹ ẹgbẹ wa ka rara. Bawo la ṣe fẹẹ tu ẹgbẹ oṣelu ka fun awọn ti wọn ki i ṣe ẹgbẹ oṣelu? Aṣiwi patapata ni, ko si nnkan to jọ bẹẹ. Gbogbo awọn oloye ẹgbẹ ADC nipinlẹ Ọṣun ni wọn ṣi wa nipo wọn, emi, Idowu Omidiji, ni alaga.


'Nnkan ti a fẹẹ sọ fawọn araalu bayii ni pe oniruuru awọn oloṣelu ni wọn ti waa darapọ mọ ẹgbẹ wa o, a si ti gba wọn wọle tori pe ijọba to wa lode bayii, paapaa julọ, lorileede Naijiria, ijọba ebi ni, ijọba amunisin ni, ijọba afiniṣẹsin ni wọn, wọn o loju aanu, gbogbo nnkan yii la fẹẹ fopin si.


'Ka maa paayan sinu oko, o to gẹẹ, awọn agbẹ o raaye lọ soko mọ, aisi eto aabo yii to gẹẹ. Ti aabo to peye ba wa, Naijiria yoo tẹ siwaju, gbogbo nnkan yii lẹgbẹ ADC fẹẹ tun ṣe.


'Ti gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ba sọ pe oun fẹẹ darapọ mọ ẹgbẹ wa, o kaabọ, gbogbo wa jọ maa ṣiṣẹ papọ ni, ṣugbọn a maa jẹ ko mọ ilana ati afojusun ẹgbẹ wa, nitori ẹgbẹ to ni ibawi lẹgbẹ wa.'

No comments:

Post a Comment