IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 6 August 2025

Idi ti a ṣe fọwọ si igbeṣe Sẹnetọ Olubiyi Fadeyi lati darapọ mọ ẹgbẹ APC - Awọn ijoye ilu Ila-Ọrangun


Awọn oloye ilu Ila-Ọrangun, iyẹn Ila-Ọrangun Traditional Chiefs, ti sọ pe awọn faramọ igbesẹ aṣofin to n ṣoju awọn eeyan aarin-gbungbun Ọṣun l'Abuja, Sẹnetọ Olubiyi Fadeyi Ajagunnla, ni didarapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC).


Fadeyi ni aṣofin keji nipinlẹ Ọṣun to kuro ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), to si darapọ mọ ẹgbẹ APC ninu oṣu keje ọdun yii, o ni ija ojoojumọ to n waye ninu ẹgbẹ ọlọnburẹda lorileede yii lo jẹ ki oun kuro nibẹ.


Lẹyin ipade kan ti awọn oloye ilu naa ṣe laipẹ yii niluu Ila-Ọrangun ni wọn ti sọ pe iṣẹ akanṣe pataki meji tijọba apapọ n ṣe lọwọ niluu awọn wa lara nnkan ti awọn fi fọwọ si igbesẹ aṣofin ọhun.


Awọn iṣe akanṣe naa; Ibudo amunawa to jẹ tijọba apapọ (Federal Government Power Sub-station) ati bi o ti ṣe ku diẹ ki aba idasilẹ ipinlẹ Igbomina di ofin, ni wọn sọ pe o ṣe pataki fun idagbasoke agbegbe awọn.


Ninu atẹjade ti Ẹlẹmọna ti Ila-Ọrangun, Oloye Agba R. A. Adedapọ fọwọ si ni wọn ti sọ pe ni bayii ti Ajagunnla ti wa pẹlu ẹgbẹ to wa nijọba apapọ, yoo lanfaani to pọ lati gbe igbesẹ lorii bi awọn iṣẹ akanṣe naa yoo ṣe yọri kiakia.


Awọn ijoye ọhun ṣeleri atilẹyin fun aṣofin wọn, wọn ni awọn yoo duro ti i lati wọle fun saa keji nitori o ti fi han pe ojulowo ọmọbibi ilu Ila-Ọrangun to nigbagbọ ninu itẹsiwaju ilu naa loun, bẹẹ ni wọn ni digbi lawọn duro fun saa keji Aarẹ Bọla Tinubu.


Wọn rọ awọn oloṣelu lati mọ pe ninu alaafia nikan ni idagbasoke ti le ba ilu, ọrọ oṣelu ko si gbọdọ da wahala silẹ niwọn igba to jẹ pe ara ilu ni wọn fẹẹ sin.


Bakan naa ni wọn sọ pe awọn ko nii faaye gba ẹnikẹni lati da rukerudo silẹ niluu Ila-Ọrangun nipasẹ imọtaraẹni nikan tabi erongba oṣelu.

No comments:

Post a Comment